Fulani darandaran meji fẹẹ fipa ba ọmọbinrin yii lo pọ, nigba ti ko gba ni wọn ṣa a ladaa ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, lawọn Fulani darandaran meji ti wọn o ti mọ orukọ wọn fẹ fipa ba ọmọdebinrin ẹni ọdun mejidinlogun kan, Abdulahi Aisha, lo pọ ni Abule Gamoleji, Lafiagi, ipinlẹ Kwara, ti wọn si ṣa a lada ṣakaṣaka lara ki awọn araalu kan too gba a silẹ tawọn Fulani naa si na papa bora. Ajọ alaabo ẹni laabo ilu, ṣifu difẹnsi, ti kede wọn gẹgẹ bii ẹni ti wọn n wa.

Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ẹsọ naa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Babawale Zaid Afolabi, fi lede lọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti sọ pe ajọ naa, labẹ isakoso ọga agba, Iskil Ayinla Makinde, gba iroyin kan pe awọn Fulani darandaran meji kan n gbinyanju lati fipa ba ọmọdebinrin kan, Aishat, lo pọ, ni Abule Gamoleji, ni Lafiagi, ti wọn ṣe e lese pẹlu ada ko too di pe awọn eniyan gba a silẹ, ti awọn Fulani naa si sa lọ, ti wọn si fi obinrin naa sinu agbara ẹjẹ.

Afọlabi ni ajọ awọn ti mu meji ninu awọn maaluu wọn, to si ti wa ni agọ ajọ naa bayii, Seriki Fulani ati olori awọn Miyeti Allah ni agbegbe naa si ti ṣeleri pe awọn yoo wa awọn ọdaran Fulani ọhun jade

 

Leave a Reply