Gomina Abdulrazak ṣabẹwo si mọlẹbi adari ẹgbẹ APC tawọn ajinigbe pa ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq, ṣiwaju awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu APC lọ sile adari awọn obinrin ninu ẹgbẹ ọhun, Olomi Abọlaji Sunday, ti awọn agbebọn ṣeku pa lati lọọ kẹdun pẹlu mọlẹbi rẹ.

Arabinrin Olomi Abolaji Sunday lo wa lara awọn mẹjọ ti awọn agbebọn naa ji gbe lasiko ti wọn n dari ayẹyẹ ibura awọn oloye ẹgbẹ APC nipinlẹ naa, eyi to waye ni Gbọngan Banquet, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ti wọn si ji awọn mẹjọ naa gbe. Ṣugbọn nigba tawọn ẹṣọ alaabo fẹẹ doola ẹmi wọn ni wọn ṣeku pa arabinrin ọhun.

Gomina Abdulrazak kẹdun iku ọmọ wọn ti awọn agbebọn da ẹmi ẹ legbodo yii pẹlu mọlẹbi. O gbadura pe ki Ọlọrun rọ awọn ẹbi loju lati le fara da iru adanu nla bayii. Bakan naa lo ni ijọba oun ko ni i kaaarẹ lori ọrọ eto aabo, ti yoo si ri i pe gbogbo awọn ọdaran ti wọn ti n fooro ẹmi awọn olugbe ipinlẹ Kwara ni ọwọ yoo tẹ lọkọọkan, ti wọn yoo si fi wọn jofin.

Bakan naa lo ṣabẹwo si awọn to mori bọ, ti wọn tun fara pa, ti wọn si wa nileewosan, o gbadura pe ki Ọlọrun tete fun wọn lalaafia.

Leave a Reply