Gomina Akeredolu ati Arẹgbẹṣọla pari ija ọlọjọ pipẹ to wa laarin wọn

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ṣe ni idunnu Ṣubu layọ fawọn alatilẹyin Minisita fọrọ Abẹle lorileede yii, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ati Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu, pẹlu bawọn agba oloṣelu ọhun ṣe gba lati pari ija ọlọjọ pipẹ to ti wa laarin wọn.

Arẹgbẹṣọla funra rẹ lo fidi eyi mulẹ lasiko to n ṣe ifilọlẹ  ọkọ nla kan tijọba apapọ ṣẹṣẹ ra si ileeṣẹ panapana to wa l’Akurẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii.

Arẹgbẹ ni bi ile nipinlẹ Ondo jẹ fun oun nitori pe ibẹ loun ti lo ọdun mejidinlogun akọkọ ninu igbesi aye oun.

O ni ọrẹ gidi loun ati Akeredolu tẹlẹ pẹlu bi gomina ọhun ṣe jẹ ọkan ninu awọn lọọya rẹ ko too gori oye gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ọsun.

Gomina ana ọhun ni oun pinnu lati wa siluu Akurẹ fun ayẹyẹ ifilọlẹ ọkọ tuntun naa funra oun, ko le da Aketi loju pe ija to wa laarin awọn ti di nnkan igbagbe.

Lati igba ti wọn ti n mura eto idibo gomina ipinlẹ Ondo to waye lọdun 2016 ni nnkan ko ti lọ deede laarin awọn ọrẹ mejeeji yi mọ.

Bo tilẹ jẹ pe abẹ asia ẹgbẹ APC ni Arẹgbẹ fi n ṣakoso gẹgẹ bii gomina Ọsun nigba naa, Oluṣọla Oke to jẹ oludije ẹgbẹ AD lo ṣatilẹyin fun, to si kẹyin si Aketi to jẹ ọrẹ rẹ ti wọn jọ je ọmọ ẹgbẹ kan naa.

Leave a Reply