Gomina Ebonyi lugbadi koronafairọọsi, aṣẹ bọ sọwọ igbakeji

Gomina ipinlẹ Ebonyi, Dave Umahi, ti lugbadi arun koronafairọọsi pẹlu awọn amugbalẹgbẹ rẹ kan.

Umahi lo kede ọrọ ọhun funra ẹ ninu atẹjade kan to fọwọ si lonii, ọjọ Abamẹta, Satide.

Atẹjade naa ṣalaye pe igbakeji gomina, Kelechi Igwe, ni yoo maa tukọ ipinlẹ naa lati oni lọ titi digba ti ara gomina yoo ya.

Lọwọlọwọ bayii, irinwo-le-mejidinlogoji (438) eeyan lo ti lugbadi koronafairọọsi nipinlẹ Ebonyi, ninu eyi ti ọọdunrun-le-mẹtadinlọgọta (357) ti ri iwosan, tawọn mẹta si ti dagbere faye.

Ẹwẹ, ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Benue ti kede pe iyawo gomina, Eunice Ortom, ọmọ rẹ atawọn oṣiṣẹ ile ijọba kan ti lugbadi koronafairọọsi.

Leave a Reply