Iṣoro Naijiria kọja eyi ti Buhari le yanju, ki ẹnikẹni ma ro pe ayipada yoo wa ṣaaju 2023 – Biṣọọbu Adeoye

Alukooro igbimọ awọn Biṣọọbu lagbaaye (World Bishops Council) nilẹ Afrika, Biṣọọbu Ṣeun Adeoye, ti sọ pe iṣoro ti orileede yii n koju lọwọlọwọ kọja agbara Aarẹ Muhammadu Buhari, nitori ogun-ẹmi ni, to si lagbara pupọ.

 

Adeoye, ẹni to tun jẹ oludasilẹ ijọ Sufficient Grace Truth Christian Church, Ọkinni, nipinlẹ Ọṣun, ṣalaye pe gẹgẹ bi Dagoni ko ṣe ri ojutuu si ọrọ apoti-ẹri Ọlọrun ninu iwe Samuel Kin-in-ni, ori karun-un, naa ni Aarẹ Buhari ko ni ipa kankan lati yanju ogun to n doju kọ orileede yii.

 

Gẹgẹ bo ṣe wi, “Ninu adura mi fun orileede yii, mo ri i pe Naijiria n wọya ija pẹlu awọn agbara okunkun, ṣugbọn a ni awọn adari ti ko le koju ogun, Igbakeji aarẹ, Yẹmi Oinbajo, nikan ni mo ri to n tiraka lati ja ija yẹn.

 

“Ko si ogun ti eeyan le ṣẹ loju-aye lai kọkọ ṣẹ ẹ ninu ẹmi. Ko si agbara eniyan to le ṣẹgun agbara okunkun. Ija ara nikan ni Aarẹ Buhari n fọkan si, wahala Naijiria si ju bẹẹ lọ.

 

“Loootọ, baba ni Buhari jẹ, a si n reti pe ko jagun fun orileede yii ni gbogbo ọna, ṣugbọn agbara rẹ ko ka a ninu ẹmi.

 

“Ọna abayọ kan ṣoṣo si wahala yii ni ki gbogbo awa ọmọ orileede yii bẹrẹ adura pe ki Ọlọrun ran Dafidi si wa lọdun 2023, ki ẹnikẹni ma ṣe ro pe ayipada kankan yoo wa ṣaaju igba idibo yẹn rara.

 

“A gbọdọ beere fun aanu Ọlọrun, ki a si fara da ohun gbogbo to ba ṣẹlẹ titi di ọdun 2023. A gbọdọ beere fun ẹni bii ọkan Ọlọrun ti yoo jẹ aarẹ wa lati iha Ila-Oorun orileede yii.

Leave a Reply