Ibọn ogoji, ọta rẹpẹtẹ, ada ati oogun abẹnugọngọ lawọn ọlọpaa ko nile Auxilliary

Ọlawale Ajao, Ibadan

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ṣi n wa Alaaji Mukaila Lamidi, ti gbogbo eeyan mọ si Auxilliary, to ti figba kan jẹ oludari ati alaga awọn to n mojuto garaaji ọkọ ero nipinlẹ Ọyọ.

Eyi ko sẹyin bi awọn ọmọọṣẹ ọkunrin naa ṣe ko ada ibọn, oogun abẹnugọngọ atawọn ohun ija mi-in loriṣiiriṣii jade, ti wọn si n ba awọn araalu ja, ti wọn n da gbogbo igboro ru.

Ohun ti ALAROYE gbọ pe o n bi awọn ọmọọṣẹ Auxilliary ninu ni bi Gomina Makinde ṣe kede iyọnipo ọkunrin naa gẹgẹ bii alaga awọn to n mojuto awọn ibudokọ nipinlẹ Ọyo.

Lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn eeyan ipinlẹ ọhun lo mu ki awọn ọlọpaa fọn sita lati koju awọn ọmọ ẹyin ọga onimọto naa. Bakan naa ni wọn gba ile rẹ to wa ni Alakia lọ. Iyalẹnu lo si jẹ pe nigba ti wọn wọnu ile naa, ti wọn fọ gbogbo rẹ tuutuu, ibọn jagamu AK 47 bii ogoji, ọta ibọn, ibọn agbelẹrọ, ada, ọbẹ, oogun abẹnugọngọ owo atawọn nnkan mi-in ni wọn ba nibẹ, ti wọn si ko gbogbo rẹ lọ.

Ṣe oju bọrọ kọ la fi i gba ọmọ lọwọ ekurọ, ko rọrun fawọn agbofinro lati wọle ọkunrin naa bẹẹ, nitori ṣe lawọn ọmọ ẹyin rẹ kọju ija si awọn agbofinro to lọ sibẹ, ti iro ibọn si n dun lakọlakọ.

Awọn eeyan adugbo Alaika, niluu Ibadan, nibi ti ọkunrin naa kọle si lo fara gba ju ninu akọlu naa, nitori iṣẹlẹ naa ko ẹmi wọn soke, ti onikaluku si n sa kijokijo pẹlu bi ọta ibọn ṣe n ro lakọlakọ, bo tilẹ jẹ pe ẹnikẹni ko ba iṣẹlẹ naa lọ.

Ṣugbọn awọn ọlọpaa pada kapa awọn eeyan naa, ti wọn si raaye wọnu ile ọhun. Koju ma ribi, gbogbo ara loogun rẹ ni Auxilliary fọrọ naa ṣe, nitori wọn ko ba ọkunrin onimọto naa nile, o ti sa lọ tefetefe.

ALAROYE gbọ pe titi di ba a ṣe n sọ yii ni awọn ọlọpaa ṣi n wa ọkunrin naa, wọn n dọdẹ rẹ ni koṣẹkosẹ, wọn fẹ ko waa ṣalaye bi awọn ibọn nla nla ti wọn ka mọ’nu ile rẹ ṣe debẹ.

Ohun ti awọn eeyan n sọ ni pe o jọ pe tirela ti gba aarin Gomina Ṣeyi Makinde ati Lamidi kọja, idi si niyi to fi yọ ọ nipo alaga ati alaamojuto awọn gareeji to fi i si. Igbesẹ yii ni a gbọ pe ko dun mọ awọn ọmọọṣẹ Auxilliary ninu ti wọn fi bẹrẹ ija igboro niluu Ibadan.

Ninu fidio to tẹ ALAROYE lọwọ nipa akọlu naa ni ẹnikan ti n ṣalaye bawọn ọlọpaa ṣe ya wọn inu ile ọga onimọto yii, ti wọn fi ibọn da batani si ara awọn mọto, oju ferese ati bẹẹ bẹẹ lọ ninu ile ọhun.

Ọpọlọpọ mọto to wa ninu ile naa lo bajẹ, tawọn gilaasi oju windo awọn ile ọhun si fọ silẹ kaakiri.

Leave a Reply