Nitori bata lasan, ọrẹ meji gun Ekene lọbẹ pa n’Iganmu

Faith Adebọla

Loootọ lawọn agba sọ pe ariyanjiyan ni i ba ọrẹ jẹ, amọ bo ba jẹ pe ariyanjiyan awọn ọrẹ mẹta yii, Adamu, Umaru ati Ekene ba ajọṣe wọn jẹ nikan ni, ọrọ iba dun, iwọ-o-fẹ, emi-o-gba to waye laarin wọn lori ọrọ bata awọ-re-baluwẹ ti wọn n pe ni silipaasi kan to waye nirọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejindinlọgbọn, oṣu Karun-un yii, ti ṣeku pa ọkan lara wọn, Ekene, ọmọọdun mẹtala pere. Niṣe ni wọn gun un nigo pa, awọn meji yooku, Ahmed, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ati Umaru Abubakar, ẹni ọdun mejidinlogun, si ti wa lakolo ọlọpaa, nibi ti wọn ti n fọrọ po wọn nifun pọ bayii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lori ikanni abẹyẹfo, tuita rẹ, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un ọhun, sọ pe, ‘Awọn aladuugbo kan ti wọn n gbe ni Iganmu, nibi tiṣẹlẹ ọhun ti waye ni wọn tẹ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Ijọra Badia laago pe awọn bọisi kan ti n ba ara wọn ja labẹ biriiji Iganmu, wọn lo da bii pe wọn ti ṣe ẹnikan leṣe gidigidi.

‘Oju-ẹsẹ naa lawọn agbofinro ti gbera lọ sibi ti wọn juwe fun wọn ọhun, amọ kankan lole i wure lọrọ awọn alajangbila yii, bi wọn ṣe ri ọkọ awọn agbofinro yii lọọọkan, igbẹ la a fẹwe, oko la a wa nnkan ọbẹ ni wọn fọrọ naa ṣe, niṣe ni gbogbo wọn fẹsẹ fẹ ẹ, ti wọn sa lọ.

‘Nigba tawọn ọlọpaa si de ojuko ibi ti wọn ti n ja labẹ biriiji naa, ọmọdekunrin yii ni wọn ba ninu agbara ẹjẹ rẹpẹtẹ’.

O lawọn ṣi ri apa ibi ti wọn ti gun un ni nnkan  nigbaaya rẹ lapa osi, ni wọn ba gbe e sinu ọkọ wọn, wọn gbe e lọ si ọsibitu Jẹnẹra Ajerọmi to wa nitosi, boya awọn dokita ṣi le rọgbọn da si i, tori o ṣi n sọ piki piki lẹẹkọọkan. Amọ bi wọn ti dọhun-un, ti wọn bẹrẹ si i fun un nitọju pajawiri lo gbẹmi mi.

O lawọn ti gbe oku naa lọ sọsibitu Jẹnẹra to wa ni Yaba, fun ayẹwo lati fidi ohun to pa a mulẹ.

Hundeyin ni awọn kan tọrọ ṣoju ẹ sọ ọ di mimọ fawọn ọtẹlẹmuyẹ pe ọrọ bata silipaasi kan lo dija silẹ. Oloogbe yii ni oun loun ni bata ti ọkan ninu wọn wọ s’ẹsẹ, o ni ko bọ bata oun foun, ṣugbọn tọhun sọ pe bata ẹ kọ, oun loun ni in, boya ọ jọra wọn ni. Eyi ni wọn fa tọrọ naa fi dija gidi, to fi dogun a n gunra ẹni nigo.

Alukoro naa ni lẹyin tawọn ọtẹlẹmuyẹ ti fimu finlẹ daadaa ni wọn kẹẹfin awọn meji yii nibi ti wọn sa pamọ si, ni wọn bi fi pampẹ ofin gbe wọn.

Wọn niyaa oloogbe naa, Chizoba Agu ti sunkun kikoro lọ sọsibitu ti wọn gbe oku ọmọ ẹ si ọhun, o si ti fidi ẹ mulẹ pe ọmọ oun ni wọn da ẹmi ẹ legbodo loootọ, o loun ran an niṣẹ lalẹ ọjọ naa ni.

Ṣa, Alukoro Hundeyin lawọn ti taari awọn afurasi mejeeji tọwọ ba yii si ẹka ti wọn ti n tọpinpin ọrọ dori okodoro ni Panti, Yaba, iwadii ijinlẹ si ti n lọ lọwọ. Lẹyin eyi lo lawọn maa foju wọn bale-ẹjọ gẹgẹ bii aṣẹ ti Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Idowu Owohunwa, pa.

Leave a Reply