Igbakeji abẹnugan Ogun ti wọn yọ nipo pe ileegbimọ lẹjọ, o ni ki wọn san biliọnu kan aabọ naira foun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 

Igbakeji abẹnugan ile-igbimọ aṣofin Ogun tẹlẹ ti wọn yọ nipo laipẹ yii, Ọnarebu Dare Kadiri, ti pe ile naa lẹjọ lori yiyọ ti wọn yọ ọ nipo, bẹẹ lo ni ki wọn san biliọnu kan aabọ ( 1.5b) owo ibanilorukọ jẹ foun.

Abẹnugan ile naa, Ọnarebu Ọlakunle Oluọmọ, ni ẹni akọkọ ti Kadiri pe lẹjọ, bẹẹ lo pe ileegbimọ lẹjọ ṣikeji.

Awijare ọkunrin yii ninu iwe ipẹjọ rẹ ti wọn kọ lọjọ kẹwaa, oṣu kẹta yii, ni pe ileegbimọ aṣofin Ogun fi ẹtọ oun du oun, pẹlu bi wọn ko ṣe gbọ alaye oun gẹgẹ bi ofin ṣe la a kalẹ.

Bakan naa lo ni ki kootu ri yiyọ nipo oun bii eyi ti ko tọ, to si jẹ ofo patapata, nitori ilana ti wọn gba ṣe e ko faaye silẹ foun lati sọ tẹnu oun.

Oludare fi kun un pe Oluọmọ to jẹ abẹnugan lo wa nidii iyọkuro oun, oun naa lo si tun ṣe alaga lọjọ ti wọn n yọ oun nipo, bẹẹ beeyan ko ba lẹni nigbimọ, to ba rojọ are, ẹbi ni wọn yoo da a.

Awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn gbe kalẹ pe ki wọn wadii oun paapaa, yatọ si akọwe ile, Oludare sọ pe gbogbo wọn ni wọn ti n fẹsun kan oun tẹlẹ, ti wọn si ti kọwọ bọwe iyọkuro nipo oun, ọna waa da ti wọn ko ni i yọ oun danu.

Fun idi eyi, olupẹjọ naa ni afi ki wọn sanwo itanran lori ohun ti wọn ṣe foun yii, nitori igbesẹ to lodi labẹ ofin ni.

Tẹ ẹ o ba gbagbe, laipẹ ni wọn yọ Oludare Kadiri nipo igbakeji abẹnugan Ogun, nitori wọn lo huwa janduku, o ba dukia awọn eeyan kan jẹ, bẹẹ lo ko awọn tọọgi lẹyin lati fa wahala, nitori nnkan eelo iforukọsilẹ ẹgbẹ APC to waye loṣu to kọja.

Leave a Reply