Ijinigbe ati gbogbo wahala awọn Fulani gbọdọ dopin nipinlẹ Ogun-OPC

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bi eeyan ba le ewurẹ ju, ẹran a maa yiju pada ti yoo bu ni jẹ. Eyi lowe ti ẹgbẹ Oodua People’s Congress (OPC) ẹka tipinlẹ Ogun, pa lọsẹ to kọja yii fawọn ajinigbe, agbebọn, afipa-ba-obinrin olobinrin lo pọ atawọn ẹni ibi yooku to n pa ipinlẹ naa lẹkun. Wọn ni o too gẹẹ, OPC ti ji giri bayii, awọn yoo gbena woju awọn ẹni ibi wọnyi, wọn gbọdọ kuro nipinlẹ Ogun raurau ni.

Oloye Adeṣina Jimọh, Adari igun OPC ti Iba Gani Adams nipinlẹ Ogun, lo ṣalaye ni kikun ninu atẹjade to fi sọ ohun ti oju awọn eeyan ipinlẹ yii n ri l’Abẹokuta, n’Ijẹbu ati Yewa ti i ṣe ẹkun mẹta ti ipinlẹ Ogun pin si.

Oloye Jimọh sọ pe akọsilẹ iye owo to jade lati ọwọ awọn ọmọ ipinlẹ Ogun sọwọ awọn ajinigbe to ji eeyan wọn laarin ọsẹ kan le ni ọgbọn miliọnu. Owo ti ko si, to jẹ ipa lawọn eeyan naa fi ko o silẹ, o ni owo to yẹ ko tun ọrọ aje ṣe to bọ sọwọ awọn apanilẹkun jaye ni.

Atẹjade naa ṣalaye nipa aisi aabo rara nipinlẹ Ogun, to bẹẹ to jẹ nigba tawọn ọlọpaa pe awọn akọroyin lọjọ karun-un, oṣu karun-un yii, pe ki wọn waa wo awọn ọdaran tawọn mu, ajinigbe ni mẹjọ ninu awọn mẹrindinlogun ọdaran ti wọn ṣafihan wọn. Awọn ti wọn ji Dokita ati nọọsi gbe lọna Abẹokuta si Ayetoto- Imẹkọ, atawọn ti wọn ṣe tiwọn lọna Ijẹbu-Ode s’Ibadan.

Ko tun ju ọjọ meji lẹyin tawọn ọlọpaa pepade akọroyin, awọn ajinigbe tun ji eeyan mẹrin mi-in gbe labule Olubọ, ni Yewa. Yoruba lawọn ti wọn ji gbe naa, wọn fi Hausa ati Fulani ti wọn jọ wa ninu ọkọ naa silẹ, wọn ko Yoruba wọgbo lọ. Bẹẹ, ẹnikẹni ko ti i ri awọn ti wọn ji gbe naa titi dasiko yii, bi wọn ku ni tabi wọn ye.

Nigba to n ṣe atupalẹ iye owo to ti ọwọ awọn ọmọ ipinlẹ Ogun bọ sọwọ awọn ajinigbe to pe ni Fulani yii, Adari OPC Ogun yii sọ pe awọn ẹbi eeyan mẹrin ti wọn kọkọ ji gbe san miliọnu mẹrin aabọ (4.5m) gẹgẹ bawọn ṣe gbọ. O ni lẹyin ti wọn sanwo naa ni wọn tu wọn silẹ tawọn eeyan gbọ yẹn.

Adeṣina ni miliọnu mẹrinlelọgbọn ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (N34. 5 Million) lawọn Fulani darandaran gba lọwọ ẹbi awọn ti wọn ji gbe nipinlẹ Ogun, ninu ijinigbe mẹta ọtọọtọ ti wọn ṣe laarin ọsẹ kan.

Lọpọ igba, awọn eeyan ti ko tilẹ da ni miliọnu kan lọwọ lawọn Fulani yii n ji gbe gẹgẹ bi Adeṣina ṣe wi, awọn ọlọja, awọn oṣiṣe ijọba atawọn ọmọ ileewe. Wọn yoo waa ko awọn ẹbi wọn sinu idaamu nla, awọn ẹbi yoo fẹrẹ le yawo lọwọ ọta wọn ki wọn too le gba ẹeyan wọn ti wọn ji gbe silẹ.

Ohun to le ju ni pe awọn mi-in yoo kowo kalẹ tan bayii, awọn ajinigbe yoo si tun pa ẹni ti wọn tori ẹ sanwo nla fun wọn.

Ṣe bi yoo ṣe waa maa lọ naa ree ti ko ni i si kinni kan ti Yoruba yoo ṣe si i? Olori APC Ogun ni rara.

‘‘A ti ṣetan ogun lati gbeja awọn Yoruba ipinlẹ Ogun. Gbogbo ijinigbe, ifipa-ba-obinrin lo pọ, ipaniyan ati didunkooko mọ ni tawọn Fulani darandaran n ṣe yii gbọdọ dopin bayii. Wọn ti ti OPC kan ogiri bayii, suuru wa ti pin.  A o ni nnkan mi-in mọ ti a le ṣe bayii ju ka gbeja ilẹ wa lọ. Gbogbo ọmọ Oodua lọkunrin lobinrin, ina fun ina ni o, ogun fun ogun.’’

Leave a Reply