Faith Adebọla
Ijọba apapọ ti sọ fun ile-igbimọ aṣofin apapọ ilẹ wa l’Abuja pe awọn fẹ ki wọn ṣofin to maa fun ijọba lagbara lati ṣakoso eto iroyin lori atẹ ayelujara, ko le ṣee ṣe funjọba lati maa ri si awọn iroyin to n gba oju opo intanẹẹti bọ sori afẹfẹ nilẹ wa.
Minisita feto iroyin, Alaaji Lai Mohammed lo parọwa yii sawọn aṣofin ọhun nibi apero itagbangba kan to waye l’Abuja, l’Ọjọruu, Wẹsidee yii.
Apero ọhun da lori abadofin kan ti igbimọ awọn aṣoju-ṣofin n ṣiṣẹ le lori lọwọ lati ṣatunṣe si ofin to rọ mọ eto igbohun-safẹfẹ nilẹ wa. Tori abadofin naa ni wọn ṣẹ pepade apero pe kawọn araalu waa sọ ero wọn lori awọn atunṣe ti wọn n gbero si ofin igbohun-safẹfẹ ọhun, oniruuru awọn ileeṣẹ ati ajọ oniroyin bii Institute for Media and Society ati International Press Center atawọn mi-in si ti sọrọ nibẹ.
Nigba to kan Alaaji Lai lati sọrọ, o ni ẹbẹ pataki kan toun fẹẹ bẹ awọn aṣofin naa ni pe ki wọn ma ṣe fi eto iṣakoso igbohun-safẹfẹ mọ lori awọn ileeṣẹ redio ati tẹlifiṣan to wa lakọọlẹ nikan, ṣugbọn ki wọn fẹ ofin naa loju, ko le ṣee ṣe fun ijọba lati maa ṣakoso awọn ileeṣẹ igbohun-safẹfẹ, ati awọn ikanni ijumọsọrọpọ to wa kaakiri atẹ ayelujara nilẹ wa.
Lai ni: “Mo fẹẹ pe akiyesi wa si i pe igbohun-safẹfẹ lori atẹ ayelujara, ati awọn ikanni ijumọsọrọpọ gbọdọ wa ninu awọn ti ofin ta a fẹẹ ṣatunṣe si yii maa kan, tori ojuṣe wa ni lati maa ṣọ ohun ti wọn n gbe jade, titi kan ikanni bii Tuita atawọn mi-in.”
O tun ṣalaye pe “Ofin ilẹ wa ko le wa labẹ ofin agbaye to ba dọrọ ibanisọrọpọ kari-aye ati awọn adehun to rọ mọ ọn. Loootọ la wa lara awọn to fọwọ siwee adehun agbaye ọhun, ṣugbọn ofin ilẹ wa ati awọn ilana tijọba la kalẹ ṣi gbọdọ lagbara ju iwe adehun agbaye eyikeyii lọ. Iwe adehun wa loootọ, amọ a n ṣofin nilẹ wa lati bojuto awọn ipo pato kan labẹle wa ni. Tori naa, mo fẹẹ da a labaa pe ka tun ọrọ yii gbe yẹwo daadaa.”
Amọ ṣa o, awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ati ajọ to wa nibi apero naa sọrọ lori ero minisita yii, wọn lawọn ko fara mọ erongba ati aba rẹ rara. Wọn ni iru ofin ti minisita yii n sọrọ rẹ maa sakoba fun ẹtọ awọn araalu ati ominira wọn lati sọrọ falala, bẹẹ ni yoo ṣepalara fun atẹ ayelujara ati ikanni ajọlo ti kaluku ti n ta ọrọ latagba. Wọn ni iru ofin bẹẹ maa tẹ ẹtọ oniroyin loju o si maa tako ofin ati ominira awọn akọroyin ati ileeṣẹ iroyin gbogbo.
Bakan naa, Abẹnugan awọn aṣoju-ṣofin ati olori wọn, Ọnarebu Fẹmi Gbajabiamila fesi lopin apero naa, o ni abadofin tawọn n gbe yẹwo yii ko kan ṣiṣakoso awọn ileeṣẹ oniroyin tabi awọn ikanni ibaniṣọrọ to wa lori atẹ ayelujara, o ni ohun ti abadofin naa n ṣatunṣe si ni awọn koko iroyin ti wọn le maa gbe sori afẹfẹ.