Ijọba fẹẹ gbogun ti awọn to n ta pọnmọ ti wọn fi kẹmika si faraalu l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Pẹlu bi awọn kan ṣe n fi ọgbọn alumọkọrọyi ko pọnmọ to ti bajẹ wọ ipinlẹ Ọṣun, ijọba ti pinnu lati bẹrẹ si i ṣayẹwọ oriṣiiriṣii pọnmọ ti wọn n ta lọja bayii, ẹnikẹni ti ajere iwa ibajẹ naa ba si ṣi mọ lori yoo kanjangbọn.

Kọmisanna fọrọ eto ọgbin ati ipese ounjẹ l’Ọṣun, Ọnarebu Adedayọ Adewọle, lo sọ eleyii di mimọ lasiko ipade kan to ṣe pẹlu ẹgbẹ awọn to n ta pọnmọ (Ponmo Dealers Association).

Adewọle, ẹni ti alakooso ileeṣẹ naa, Adegbemisoye Fayọyin, ṣoju fun sọ pe o jẹ nnkan to n kọ ijọba lominu pẹlu bi awọn kan ko ṣe bikita nipa ohun ti wọn n ta fawọn araalu lati jẹ, ati bi awọn araalu gan-an ko ṣe naani orisun nnkan ti wọn n fi sẹnu mọ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, awọn kọlọransi kan ti n ko awọn pọnmọ ti wọn n fi oogun fọmalin ṣe wọ ipinlẹ Ọṣun, eleyii to si lewu pupọ fun ilera ẹnikẹni to ba jẹ ẹ, idi si niyi tijọba fi pinnu lati ba awọn ẹgbẹ naa ṣepade nitori ijọba fẹẹ gbe igbesẹ to lagbara lori wọn.

Ṣaaju ni ọga agba lẹka awọn dokita ẹranko, Dokita Abọsẹde Ọlatokun, ti ni awọn yoo bẹrẹ si i ṣayẹwo si ara awọn pọnmọ ti wọn n ta kaakiri ọja bayii gẹgẹ bi awọn ṣe maa n ṣe si awọn maaluu atawọn alapata.

Ọlatokun waa rọ awọn ẹgbẹ onipọnmọ lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba, nitori irọrun wọn naa ni irọrun araalu, o ran wọn leti pe pọnmọ wa lara ounjẹ to gbajumọ ju laarin awọn eeyan lasiko yii, idi si niyẹn ti amojuto to peye fi gbọdọ wa nipa rẹ.

Alaga ẹgbẹ onipọnmọ l’Ọṣun, Alhaji Adebimpe, dupẹ lọwọ ijọba fun igbesẹ ti wọn gbe, o ṣalaye pe oniruuru ipenija lawọn ti koju latẹyin ninu erongba awọn lati ṣafọmọ ẹgbẹ naa, o si jẹjẹẹ atilẹyin ẹgbẹ fun ijọba Gomina Oyetọla.

Leave a Reply