Ijọba lu awọn mọto to lufin irinna ni gbanjo l’Ekoo

Jide Alabi

Mọto oriṣiiriṣii bii mẹtalelọgọrin (83) ni ijọba Eko lu ni gbanjo lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

ALAROYE gbọ pe kaakiri awọn ibi kan nipinlẹ naa lọwọ ti tẹ awọn eeyan to lu ofin eto irinna l’Ekoo, awọn mọto ti wọn gba nidii wọn ni ijọba lu ta ni gbanjo lẹyin ti kootu alagbeeka to gbọ ẹsun ti wọn fi kan awọn eeyan ọhun ti fun ijọba laṣẹ lati ta wọn danu.

Alakooso eto ọhun, Arabinrin Arinọla Ọgbara, ṣalaye fawọn oniroyin ni Alausa, Ikẹja, pe eto naa ko ni kọnu-n-kọhọ kankan ninu, ojutaye lawọn fi ṣe, ti gbogbo eeyan si ri i.

“Gbogbo ilana to yẹ ki a tẹle pata la tẹle ki a too lu awọn mọto ọhun ta ni gbanjo. Ninu awọn ta a mu la fun ni anfaani lati sanwo itanran, eleyii si ni i ṣe pẹlu iru ẹṣẹ ti eeyan ba ṣe atawọn ẹri gidi to ba mu wa siwaju k̀ootu alagbeeka to n gbọ ẹjọ ọhun.

“Ti a ba wo o daadaa, iwakuwa ti awọn awakọ mi-in maa n wa, ti wọn ki i pa ofin irinna mọ, ti ṣakoba fun ọpọlọpọ eeyan. Aimọye dukia lo ti sọnu, aimọye ẹmi lo ti ṣofo. Ohun ti awọn amọye si sọ ni pe o ṣe pataki ki a fọ ipinlẹ Eko mọ lọwọ awọn dẹrẹba oniwakuwa ti wọn maa n ṣe bii ẹni pe ko sẹni to le mu awọn.”

Ṣa o, alaga igbimọ to lu mọto awọn eeyan ta ni gbanjo yii ti sọ pe ki i ṣe pe awọn fẹẹ mọ-ọn-mọ fiya jẹ enikẹni, ṣugbọn koko ohun to mu ijọba gbe igbesẹ ọhun ni lati fopin si iwakuwa oriṣiiriṣii tawọn kan maa n wa mọto laarin ilu.

O ni, “Emi ko ri ohun ta a waa ṣe lon-in bii ẹni lu mọto awọn eeyan ni gbanjo, loju temi, bii ẹni pe a waa kọ awọn eeyan lẹkọọ bi eeyan ṣe maa n pa ofin mọ laarin iIu ni. Kọmiṣanna ọlọpaa ti sọ pe ka jade, ki a lọọ pa eto ofin irinna ọkọ mọ gẹgẹ bii ẹṣọ agbofinro, o si di dandan ki a ṣe bẹẹ ki wọlu-wọpọ ọkọ le dopin nigboro Eko.

 

Leave a Reply