Faith Adebọla, Eko
Bẹrẹ lati ọjọ kẹrinla, oṣu kejila, ta a wa yii, ijọba apapọ ti kede pe awọn ti din owo-epo bẹntiroolu walẹ, laarin naira mejidinlaaadọsan-an (#168) si naira mejilelaaadọjọ (#162) ni wọn yoo maa ta a bayii.
Minisita fun ọrọ awọn oṣiṣẹ, Chris Ngige, lo kede eyi lowurọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, nigba to n jabọ ipade ti wọn ṣe pẹlu ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ilẹ wa, iyẹn NLC ati TUC.
Ngige ni awọn tun ti gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo tubọ mojuto bi owo-epo ko ṣe ni i maa ṣe segesege, ti yoo si tubọ rọju faraalu.
Lati nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ọjọ Aje, Mọnde, lawọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ ọhun ati awọn ti ijọba apapọ ti tilẹkun mọri l’Abuja, lati fori kori lori ọrọ ẹkunwo owo-epo to n ja ranyin nilẹ wa. Nnkan bii aago meji ọganjọ oru nipade too pari.
Titi dasiko yii, nnkan bii aadọsan-an naira (#170) ni wọn n ta jala epo bẹntiroolu, latari bi ẹka ileeṣẹ ijọba to n ṣakoso epo rọbi, NNPC, ṣe buwo le iye tawọn olokoowo yoo maa gbe epo jade loṣu kọkanla to kọja yii, leyii to mu ki ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fariga.