Ile alaja mọkanlelogun wo le awọn to n ṣiṣẹ nibẹ lori l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

 Titi dasiko yii ni ko ti i sẹni to le sọ pato ipo tawọn oṣiṣẹ rẹpẹtẹ atawọn ọga wọn to wa nigba ti ile alaja mọkanlelogun kan da wo mọ wọn lori laaarọ ọjọ Aje, Mọnde yii.

Iṣẹlẹ yii waye nibi ti iṣe ikọle ti n lọ lọwọ lori ile awoṣifila ọhun to wa lọna Gerrard, n’Ikoyi, l’Erekuṣu Eko.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo ati awọn ẹṣọ ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri tijọba ipinlẹ Eko ati apapọ ni wọn ti wa nibi iṣẹlẹ naa, ti wọn si ti n fi ẹrọ katakata ko awoku ile naa kuro lati doola ẹmi awọn to wa labẹ ẹbiti naa, tabi ki wọn ko oku awọn to ba doloogbe jade.

Lara awọn to n ṣiṣẹ lọwọ nibẹ ni ajọ LASEMA, NEMA, ọlọpaa, panapana, ati awọn oṣiṣẹ eleto ilera.

Ko ti i sẹni to mọ pato ohun to ṣokunfa ajalu naa, ṣugbọn Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.

Leave a Reply