Ile-ẹjọ fagi le idibo ijọba ibilẹ ti wọn di l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Adajọ ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to fikalẹ siluu Oṣogbo, Onidaajọ Nathaniel Emmanuel Ayọọla, ti sọ pe idibo ijọba ibilẹ to waye nipinlẹ Ọṣun lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ko lẹsẹ nilẹ.

Onidaajọ Ayọọla sọ pe ki gbogbo awọn alaga kansu atawọn kansẹlọ naa ko angara wọn pada sile onikaluku.

O ni eto idibo ti ajọ OSIEC ṣe naa ta ko abala ikọkandinlọgbọn ati ikejilelọgbọn ofin idibo ti wọn mu atunṣe ba lọdun 2022.

A oo ranti pe ẹgbẹ oṣelu PDP lo lọ si kootu ṣaaju idibo naa pe ki ile-ẹjọ ka ajọ OSIEC lapa ko lori idibo naa, ti ajọ OSIEC si sọ pe awọn lẹtọọ labẹ ofin lati ṣe e.

Leave a Reply