Faith Adebọla
Ile-ẹjọ Majisreeti kan to fikalẹ siluu Akurẹ, nipinlẹ Ondo, ti paṣẹ pe odidi ọdun kan gbako ni Abilekọ Oluwatoyin Olusa yoo fi faṣọ pempe roko ọba lẹwọn latari ẹsun ṣiṣeku-pa ọkọ rẹ, Oloogbe Adeyinka Olisa, ti wọn lo da omi gbigbona le lori.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, nidajọ naa waye.
Ninu alaye ti awọn agbẹjọro meji ti wọn ṣoju fun ijọba, Ọgbẹni Fẹmi Emodamọri ati Ṣọla Agunloye, ṣe, wọn sọ pe agbegbe kan ti wọn n pe ni Ijọka, lawọn tọkọ-taya naa n gbe niluu Akurẹ, iṣẹ ayẹwe owo wo lọkunrin naa n ṣe nileewe ijọba School of Health Technology, to wa l’Akurẹ, nigba aye ẹ.
Wọn ni aawọ nla kan ti wa laarin oun atiyawo rẹ yii lasiko ti iṣẹlẹ iku rẹ waye, ara ọkunrin naa ko si ya daadaa lasiko ọhun, bo tilẹ jẹ pe wọn ṣi jọ n gbe papọ, iyawo yii ko si ṣaajo ẹ bo ṣe yẹ rara. Bẹẹ igbeyawo wọn ti lọjọ lori, tori ọdun mẹtalelogun sẹyin ni wọn fẹra wọn.
Wọn ni Ioṣu kọkanla, ọdun 2017, lọkunrin naa ṣubu ninu ile nibi toun atiyawo rẹ ti n ṣe fa-a-ka-ja-a lọwọ, ṣugbọn kaka ti olujẹjọ iba fi ṣaajo rẹ, niṣe lo lọọ fibinu gbe omi gbigbona, to si yii da le oloogbe ọhun lori mọlẹ, niyẹn ba fara pa yannayanna, wọn ni gbogbo ara ẹ lo bo yanmọkan.
Bo tilẹ jẹ pe awọn alaaanu kan laduugbo gbe e lọ sọsibitu, ko ju ọsẹ meji lọ to fi dagbere faye nileewosan ti wọn gbe e lọ. Ayẹwo iṣegun si fihan pe iṣoro eemi ati ara to fi ṣeṣe lo ṣokunfa iku rẹ yii.
Wọn lobinrin yii jẹbi ẹsun ṣiṣe akọlu lọna to lewu, ṣiṣe ẹlomi-in leṣe ati mimọ-ọn-mọ huwa ika ti wọn fi kan an, awọn ẹsun naa si ta ko isọri ọtalenirinwo o din marun-un (355) iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ Ondo.
Ninu idajọ rẹ, Adajọ Ruth Olumilua sọ pe ẹri fihan pe olujẹjọ yii jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an, o ni olupẹjọ ti pese ẹri to to lati fidi ẹsun rẹ mulẹ.
O ni bo tilẹ jẹ pe ọdaran naa ti bẹbẹ pe kile-ẹjọ ṣiju aanu wo oun, ati nitori ko le tọju awọn ọmọ toloogbe fi silẹ lọ, sibẹ, ẹlẹṣẹ ki yoo lọ lai jiya.
Adajọ Olumilua ni ki olujẹjọ naa lọọ ṣẹwọn ọdun kan, tabi ko san owo itanran ẹgbẹrun lọna igba (N200,000) naira.