Ile-ẹjọ sun igbẹjọ Nnamdi Kanu si ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹwaa

Faith Adebọla

Ọjọ kọkaknlelogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ni wọn sun ẹjọ ajijagbara ọmọ ilẹ Ibo nni, Nnamdi Kanu si bayii. Eyi ko ṣẹyin bi ọkunrin naa ko ṣe yọju sile-ẹjọ nitori pe agbẹjọro rẹ, Ifeanyi Ejiofor, sọ pe awọn ti kọwe si kootu pe ki wọn gbe ọkunrin to n ja fun idasilẹ orileede Biafra naa kuro ni akata DSS, ki wọn gbe e lọ si ọgba ẹwọn ki awọn to ba fẹẹ ri i le maa ni anfaani lati ri i. Nidii eyi ni ọkunrin naa  ko fi wa gẹgẹ bi agbẹjọro rẹ ṣe sọ.

Ṣugbọn agbẹjọro ijọba, M.B Abubakar, sọ pe oun ṣetan lati tẹsiwaju ninu ẹjọ naa, ki oun si wi awijare toun bo tilẹ jẹ pe ẹni ti wọn fẹẹ ba rojọ ko si nile-ẹjọ

Lẹyin eyi ni Adajọ Binta Nyako to yẹ ko gbọ ẹjọ ọhun sọ pe niwọn igba ti Nnamdi kanu ko ti si ni kootu, igbẹjọ ko le waye. Lo ba sun ẹjọ naa si ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii.

Tẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni wọn ṣu ajijagbara Biafra naa rugudu lati orileede Kenya wa si Naijiria, ti wọn si ni ko waa jẹjọ ẹsun ọdaran, ipaniyan idaluru ati bẹẹ bẹẹ lọ ti wọn fi kan an

 Ọdun 2017 ni wọn ti n ba a ṣẹjọ naa ko too di pe o sa kuro ni Naijiria, ti ko si pada wa titi oṣu keje, ọdun yii, ti wọn gbe e wale lati orileede Kenya

Leave a Reply