Ileeṣẹ ọlọpaa ti gbe Wakili lọ sọsibitu, wọn lara rẹ ko ya, bẹẹ ni wọn mu awọn OPC to mu Fulani naa

Faith Adebọla

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti sọ pe awọn maa ri i pe idajọ ododo waye lori ọrọ Seriki Fulani darandaran kan, Iskilu Wakili, tọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ Oodua People’s Congress, OPC, ba lọjọ Aiku, Sannde yii. Wakili yii ni wọn fẹsun kan pe oun lo n ki awọn Fulani laya lati maa ṣọṣẹ oriṣiiriṣii fawọn agbẹ lagbegbe naa, to si n fojoojumọ dun mọhuru-mọhuru m’awọn araalu atawọn ẹṣọ alaabo. Abule Kajọla, to wa laarin ilu Ayetẹ si Idere, lọkunrin naa pagbo awọn maaluu rẹ si, pẹlu ọgọọrọ awọn Fulani darandaran ti wọn sọ ibẹ di ibuba wọn.

Ninu atẹjade pataki kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, CSP Fadeyi Olugbenga, fi sode nipa iṣẹlẹ ọhun lọjọ Aiku, Sannde, lo ti fidi ẹ mulẹ pe afurasi ọdaran Fulani naa ti wa lahaamọ awọn, awọn si ti bẹrẹ iṣẹ iwadii ni pẹrẹu lori ọrọ naa.

Atẹjade naa ka lapa kan pe:

“Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ fasiko yii kede faraalu pe, ni nnkan bii aago mẹsan-an owurọ ọjọ keje, oṣu kẹta yii, a gbọ pe awọn eeyan kan, ta a waa mọ si ọmọ ẹgbẹ OPC ya bo agbegbe Kajọla, ni Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ, wọn fẹẹ mu ọkunrin Fulani kan ti wọn n pe ni Wakili, ẹni ti wọn fẹṣun kan pe oun lo n ṣagbatẹru, to si wa lẹyin awọn iwa ọdaran oriṣiiriṣii to waye nibi ti wọn ti ṣakọlu sawọn agbẹ Yoruba lori ilẹ wọn.

“Gbara ta a ti gbọ nipa igbesẹ yii nileeṣẹ ọlọpaa Ọyọ ti bẹrẹ iwadii, a si ri i pe loootọ lawọn ọmọ OPC lọ si Kajọla, nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, wọn dana sun ile Wakili, wọn si sun obinrin kan ta a o ti i mọ orukọ ẹ gan-an mọle naa, lẹyin eyi ni wọn mu Wakili, ẹni tọjọ ori ẹ to ọdun marundinlọgọrin, ti ko si riran daadaa mọ, wọn tun mu awọn meji mi-in pẹlu ẹ, wọn si ti fa wọn le ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ. Awọn mẹtẹẹta ti wa lakolo wa, bo tilẹ jẹ pe kọmiṣanna ọlọpaa ti paṣẹ pe ki wọn gbe Wakili lọ sọsibitu fun itọju, tori o han pe ara rẹ ko ya, amọ a ti n ba iṣẹ iwadii lọ lọdọ awọn awọn meji to ku, atawọn ọmọ ẹgbẹ OPC kan ta a fura pe wọn lọwọ ninu bi wọn ṣe dana sun ile Wakili.

“Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ fẹẹ mu da gbogbo araalu loju pe ẹnikẹni tabi awọn eeyan kan, lai fi ti ẹya tabi ilu ṣe, to ba jẹbi iwa ọdaran nipinlẹ yii ko ni i lọ lai jiya, a maa mu irufẹ ẹni bẹẹ, a si maa fẹsẹ ofin tọ ọrọ wọn.

“A fẹ karaalu mọ pe a o ni i figba kan bọkan ninu lori ọrọ yii, a maa ṣewadii to lọọrin lori ẹ, inu wa yoo si dun tawọn eeyan ba le ran wa lọwọ lati sọ lori awọn ohun ti wọn mọ to ṣe koko, ki ẹnikẹni to ba ni ẹsun lodi si Iskilu Wakili yii ma ṣe lọra lati fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, lẹka awọn ọtẹlẹmuyẹ ni Iyaganku, Ibadan. A o ni i darukọ onitọhun ti o ba fẹ ka darukọ oun.”

Bayii ni ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ.

Leave a Reply