Imaamu ba iyawo oniyawo lo pọ, lọkọ ba gun un pa

Bo tilẹ jẹ pe Umaru Jubrin to gun baba imaamu kan torukọ ẹ n jẹ Alaaji Attahiru Alhassan, pa  ti wa latimọle, ti ko le jade lakolo ọlọpaa, ajule ọrun ni Baba Imaamu wa ni tiẹ. Bẹẹ, nitori ibalopọ aitọ to ṣe ni. Umaru lo fi irin gun un lọrun, to fi dẹni to faye silẹ, to gbọrun lọ.

Ilu kan ti wọn n pe ni Enagi, ni Minna, ni wọn ti fi Alaaji Attahiru jẹ olori mọṣalaaṣi agba (Chief Imam). Ṣugbọn baba naa n yan iyawo keji ti Umaru fẹ sile lale, wọn jọ n ba ara wọn ṣere wamọwamọ.

Umaru, ẹni ọdun marundinlogoji (35) ko mọ, afi lọsẹ to kọja yii to ba iyawo rẹ kekere naa pẹlu Baba Imaamu lori bẹẹdi nihooho, ti wọn n ṣere oge.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye fawọn akọroyin nigba tawọn ọlọpaa fi oju rẹ han ni olu ileeṣe wọn ni Minna, lọjọ Iṣẹgun to kọja. Umaru sọ pe oun pade Alaaji Attahiru lọjọ iṣẹlẹ naa, oju oun bayii lo ṣe wọle alajọgbe oun kan nitosi ibẹ.

O ni iyawo oun si ti kọkọ sọ foun tẹl pe oun fẹẹ lọọ ṣegbọnsẹ lẹkule, oun si ni ko si wahala, ko maa lọ.

O ni nigba toun reti obinrin naa to to wakati kan ti ko pada, oun pinnu lati wa a lọ sibi to ti lọọ ṣegbọnsẹ, afi boun ṣe gbọ ohun rẹ ninu ile ti Baba Imaamu wọ lọ naa.

‘Bi mo ṣe wọle ni mo ba Baba Imaamu nihooho lori bẹẹdi pẹlu iyawo mi, wọn n ba ara wọn sun. Mi o wi nnkan kan, mo kan kuro nibẹ, mo gba ọdọ ẹgbọn mi lọ lati ṣalaye ohun ti mo ri fun un ni. Lẹyin igba yẹn ni Baba Imaamu tun waa ranṣẹ pe mi pe ki n wa, inu bi mi. Ibinu yẹn naa lo wa lara mi nigba ti wọn n ba mi sọrọ lori ohun to ṣẹlẹ, bi mo ṣe gba irin ti wọn mu dani niyẹn ti mo fi gun wọn lọrun.’’ Bẹẹ ni Umaru wi.

O sa lọ nigba to ri i pe Baba Imaamu ti ku latari irin to fi gun un lọrun yii, ṣugbọn awọn ọlọpaa pada ri i mu nibi kan ti wọn n pe ni Abule Batati. Ẹni ọdun mejidinlaaadọta (48) ni Baba Imaamu to doloogbe, wọn ti ni Umaru to gun un pa yoo foju bale-ẹjọ sa.

Leave a Reply