Iru ki waa leleyii, olukọ fasiti ku sinu ọkọ rẹ l’Akungba Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Olukọ agba kan ni Fasiti Adekunle Ajasin to wa niluu Akungba Akoko, Dokita Ọlatunde Adegbuyi, ni wọn deedee ba oku rẹ ninu ọkọ ayọkẹlẹ kan lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ ta a wa yii.

Akọroyin wa fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ẹnikan to jẹ oṣiṣẹ fasiti ọhun pe awọn eeyan to wa lagbegbe ibi tiṣẹlẹ yii ti waye ni wọn kọkọ ṣakiyesi oloogbe naa nibi to sọ ori kọ si ninu ọkọ rẹ nitosi ọgba fasiti naa.

Dokita Adegbuyi ni wọn lo jẹ olukọ lẹka tí wọn ti n kọ nipa imọ awọn ohun alumọọni ilẹ (Geology) ko too fẹyinti lọdun diẹ sẹyin, bo tilẹ jẹ pe awọn alasẹ fasiti ọhun tun pada fun un niṣẹ mi-in ṣe lẹyin to fẹyinti tan.

Ko sẹni to le sọ ohun to pa ọkunrin naa.

Leave a Reply