Iyabọ Ojo ati Princess ṣewọde lọ si Panti, wọn lawọn ọlọpaa ko gbọdọ tu Baba Ijẹṣa silẹ

Faith Adebọla, Eko

Gbajugbaja oṣere-binrin onitiata ilẹ wa, Iyabọ Ojo, alawada oṣere ẹlẹgbẹ ẹ mi-in, Damilọla Adekọya ti ọmọ ti wọn ni Baba Ijẹṣa fipa ba lo pọ wa lọdọ rẹ, atawọn ololufẹ wọn lọọ ṣewọde lagọọ ọlọpaa to wa ni Panti, ni Yaba, laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee yii, wọn lawọn o ni i gba kawọn ọlọpaa tu ọkunrin naa silẹ, tabi ki wọn gba beeli rẹ, afi to ba foju bale-ẹjọ.

Ninu fọran fidio kan tobinrin naa gbe sori ẹrọ ayelujara instagiraamu rẹ, tagbara-tagbara lo fi n pariwo pe ko saaye fun ojooro tabi magomago ninu iwadii tawọn ọlọpaa lawọn n ṣe lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan Baba Ijẹṣa, wọn gbọdọ fẹsẹ ofin tọ ọ bo ṣe yẹ ni.

Lara ọrọ t’Iyabọ Ojo sọ niwaju ẹka ileeṣẹ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Panti ni pe awọn ti n hu u gbọ pe awọn ọlọpaa fẹẹ tu Baba Ijẹṣa silẹ lọjọ Furaidee yii, wọn ni iwa abosi lawọn agbofinro fẹẹ hu yẹn.
Iyabọ Ojo tun sọ pe oun le ṣẹlẹrii ta ko Baba Ijẹṣa nile-ẹjọ tori oun mọ awọn iwakiwa to kun ọwọ afurasi ọdaran naa.

“A ti wa ni Panti, a wa nibi, a o ti i kuro. A o ni i jẹ ki wọn fun Baba Ijẹṣa ni beeli. A maa jọ fa a ni, a o ni i gba.”

Lẹyin eyi ni Iyabọ Ojo tun gbe fidio mi-in sori ikanni rẹ, nibi toun ati awọn ọjẹwẹwẹ onitiata kan atawọn ololufẹẹ wọn ti jokoo sile Iyabọ lẹyin ti wọn kuro ni Panti. Iyabọ sọrọ nibẹ pe gbogbo ohun to ba gba lawọn maa fun un, o ni niṣe loun n reti kawọn eeyan ti awọn lẹyin, tori awọn o fẹ iru eeyan to n ṣe palapala bẹẹ lagbo awọn onitiata.

Leave a Reply