Kayeefi kan ree o! Ọmọ ọdun meje to digunjale n’Ibadan ni: Ile mẹrin ni mo ti fọ laarin ọjọ meji

Ọlawale Ajao, Ibadan
Ko si bi eeyan yoo ṣe gburoo ọmọ naa ti ọjọ iwaju ẹ ko ni i maa kọ oluwarẹ lominu, abi nigba ti ọmọ ti ko ju ọmọọdun meje pere lọ ba yan iṣẹ ole laayo nkọ.

Ọmọdekunrin naa, Ahmed Oni, ẹni ta a fi ojulowo orukọ ẹ bo laṣiiri, lo fi ada ṣilẹkun ile aladuugbo rẹ lagbegbe Olomi, n’Ibadan, lasiko ti awọn onile ọhun ko si nile, to si ji wọn lowo ati foonu ko lọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii.
Pabanbari ibẹ ni igboya buruku ti ọmọdekunrin naa ni. Ọmọọọdun meje pere ni, iwe kin-in-ni lo ṣi wa nileewe alakọọbẹrẹ, sibẹ igboya ti ọmọde yii ni ju tọmọ ogoji ọdun mi-in lọ. O kọkọ lọọ ṣi wọduroobu aṣọ to wa ninu yara iyaale lanlọọdu naa, o tu gbogbo aṣọ to ba nibẹ yẹbẹyẹbẹ, o si ko ẹgbẹrun mẹrin Naira (₦4,0000) to ba nibẹ sapo pẹlu foonu meji to ti kọkọ ri ninu ile naa ṣaaju.
Lẹyin to tu yara iyawo keji naa tan, jagunlabi tun lọ si ile idana, o fara balẹ se irẹsi, o si jẹ ẹ tẹ ara rẹ lọrun, o tun mu miliiki to ba ninu ile idana nibẹ le e. Nibi aye ba kuku ti ba ni la a ti i jẹ ẹ.
Baba kan to n jẹ Hassan Fatai ni wọn lo ni ile ọhun, Oni si ti mọ pe Ọgbẹni Fatai atawọn iyawo ẹ mejeeji pẹlu awọn ọmọ wọn ki i si nile lojumọmọ laarin ọsẹ, bi wọn ba ti jade nile laaarọ, o tun di irọlẹ mọ ọwọ alẹ ki wọn too dari de. Ohun to jẹ ki ọmọ yii fara balẹ pẹ daadaa ninu ile onile ọhun ree.

Nigba to di ọwọ ọsan, o woye pe ounjẹ aarọ ti oun jẹ ti da ninu oun, ebi ti de. N lo ba tun gbe omi irẹsi mi-in lena, o si fi ẹsẹ kan jade sita lati lọọ tọju awọn foonu pẹlu ẹgbẹrun meji Naira ninu owo to ji ṣọwọ iya rẹ agba nile. Wọn ni nigba ti iyẹn si bi i leere ibi to ti ri awọn foonu ọhun, niṣe lo sare jade, o ni oun n pada bọ laipẹ.
Nigba ti yoo fi pada sinu ile to ti n jale, irẹsi to n se lọwọ ti fẹẹ jona tan, o jẹ iwọnba to ṣee jẹ nibẹ, o si ko gbogbo ẹran to wa ninu iṣaasun ọbẹ naa jẹ tan patapata. O jọ pe didun ọbẹ naa lo mu un tun irẹsi ọhun se lẹẹkeji. O si ri i daju pe eyi ti oun ṣe lẹẹkan yii pọ daadaa ju takọkọ lọ. O jẹun lajẹyo tan, o tun bu iyooku sinu kula kan to ba ninu ileedana nibẹ. Iyẹn lo pinnu lati gbe lọ sile gẹgẹ bii ounjẹ alẹ lẹyin to ba pari gbogbo iṣẹ to n ṣe lọwọ ninu ile naa.
Ori isinmi ounjẹ to jẹ yii lo wa to ti gburoo ẹsẹ nita lọhun-un, n lo ba gba ile idana bọ si ọọdẹ, o si gba aarin ọọdẹ bọ si ẹyinkule. Ṣugbọn bi oun ṣe ti inu ile gburoo ẹsẹ awọn to n bọ lati ita, bẹẹ ni Musbau, ọkan ninu awọn ọmọ baba onile naa to n wọle bọ, gbọ girigiri ẹsẹ lọ sọna ẹyinkule, wọn si ba jagunlabi nibi to lugọ si. N ni wọn ba pe awọn obi wọn pẹlu gbogbo araadugbo le e lori.
Musibau ṣalaye pe “ẹyinkuke lọmọ yẹn sa lọ nigba to gburoo ẹsẹ wa nigba ti a n bọ ninu ile. A ri i pe niṣe ni wọn ṣi gbogbo ilẹkun inu ile silẹ, ti wọn kan rọra pa a de gẹngẹrẹ lasan. A waa ba ọmọ yẹn lẹyinkule. O sọ fun wa pe ọmọkunrin kan lo ṣilẹkun to ji awọn nnkan wa, to si tun se raisi wa jẹ ninu ile wa.
Ọlọrun ṣe e, o loun mọ ọmọ yẹn daadaa, o si gba lati mu wa lọ sibi to wa. Ṣugbọn a ko ri ọmọ kankan nibi to mu wa lọ. O ni inu kula kan bayii lọmọ yẹn bu irẹsi to se si, ati pe oun mọ ibi to gbe kula raisi yooku yẹn si. O gbe kula jade fun wa loootọ, ṣugbọn a ko ri ọmọ to sọ pe o tọju ounjẹ yẹn sibẹ.

“O ni ka fọkan balẹ, oun maa mu ọmọ naa waa fun wa nibikibi ti oun ba ti ri i. Nibi ti ara ti bẹrẹ si i fu wa si i niyẹn pe o ni lati mọ nipa gbogbo nnkan wọnyi ko too pada jẹwọ fun wa pe oun gan-an ni”.
Bi eeyan ba ka ole mọ idi dukia ẹ bẹẹ, ṣebi niṣe ni inu ẹni maa n dun pe Olodumare fi ọta ẹni le ni lọwọ. Ṣugbọn inu awọn agbalagba to n gbe inu ile yii ko dun rara. Idi ni pe ọmọ yii ti kere ju fun nnkan to danwo yii, wọn n ronu ohun ti iru ọmọ naa le ya siluu bo ba ba iru iwa bayii dagba.
Ko wu wọn lati fiya jẹ ọmọ yii, sibẹsibẹ, wọn ni lati gbe igbesẹ to le ran an lọwọ lati ma le jale mọ. Iyẹn ni wọn ṣe fi ọrọ rẹ to awọn ẹṣọ alaabo ta a mọ si fijilante leti.

Nigba to n royin bo ṣe ṣiṣẹ ibi naa, Oni sọ pe ẹgbẹrun meji Naira (N2000) pere loun ri ji ninu ile naa, ki i ṣe ẹgbẹrun mẹrin Naira ti awọn onile n pariwo.
Gẹgẹ bii alaye to ṣe “ada ni mo fi ja kọkọrọ ẹnu ilẹkun ile yẹn ti mo fi wọle. Tuu taosan (ẹgbẹrun meji Naira) pere ni mo ri mu nibẹ. Mo si jẹ raisi ati ẹran pẹlu miliiki ti mo ba ninu ile nibẹ.

“Nigba ti awọn ọmọ onile yẹn de, wọn ni ta lo ṣilẹkun fun mi ti mo fi wọle, mo purọ fun wọn pe ọmọkunrin kan bayii lo jalẹkun wọnu ile wọn to si ji awọn nnkan wọn ko lọ.”

“Eyi kọ nigba akọkọ ti mo maa ṣe bayii, ile mẹrin ni mo ti fọ laarin ọjọ meji lọsẹ yii, ti mo si ji awọn nnkan ti mo ba nibẹ ko too di pe ọwọ tẹ mi lọjọ Tọsidee.”

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, mẹkaniiki ọkada ni baba ọmọ to jale yii, awọn fijilante si ti kọwọ ẹ bọ iwe adehun pe o ni lati tọju ọmọ naa daadaa. Bi bẹẹ kọ, ti ọwọ ba tun tẹ ẹ fun ole jija tabi iwa ọdaran mi-in nigba mi-in, ohun toju oun atọmọ naa ba ri, ki wọn yaa fara mọ ọn ni.

Leave a Reply