Ọwọ tẹ Lekan, ọmọ yahoo to fi mọto pa ọlọpaa l’Omu-Aran

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ile-ẹjọ Magistreeti kan to wa niluu Ilọrin, ti paṣẹ pe ki wọn ju ọmọ yahoo kan, Babatunde Lekan, sẹwọn fẹsun pe o fi mọto pa ọlọpaa kan l’Opopona Oro si Omu-Aran, nipinlẹ Kwara, to si sa lọ.
Agbefọba, Insipẹkitọ Innocent Owoọla, sọ fun kootu pe lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, ni arakunrin kan, Suraju, mu ẹsun lọ si olu ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, pe mọto kan gba ọlọpaa ni Opopona Oro si Omu-Aran, ti onimọto naa si sa lọ. O tẹsiwaju pe wọn sare gbe ọlọpaa ọhun lọ si ileewosan kan ti wọn ko darukọ niluu naa, sugbọn ọlọpaa naa ku loju-ẹsẹ.
Innocent sọ pe ni kete ti wọn mu ẹsun lọ ni iwadii ti bẹrẹ, ti wọn si mu afurasi naa. O jẹwọ fun ile-ẹjọ pe loootọ loun fi mọto pa ọlọpaa, ati pe iṣẹ yahoo loun yan laayo.
Agbẹjọro Lekan rọ ile-ẹjọ pe ko ṣiju aanu wo onibaara rẹ, ko gba beeli, rẹ ṣugbọn Onidaajọ Zainab Usman, sọ pe iwa ọdaran nla ni afurasi naa hu, fun idi eyi, o paṣẹ ki wọn lọọ sọ ọ sẹwọn ni Oke-Kura, niluu Ilọrin.
Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ si ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, ọdun yii.

Leave a Reply