Korona: eeyan mẹrin dagbere faye, ojilelẹẹẹdẹgbẹta tun lugbadi ẹ l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

 Ajo to n ri si idena atankalẹ arun lorileede yii, NCDC, ti kede pe, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, eeyan ojilelẹẹẹdẹgbẹta ati meji (542) lo ṣẹṣẹ lugbadi arun aṣekupani Koronafairọọsi nipinlẹ Eko, nigba tawọn mẹrin doloogbe.

Ninu atẹjade ti ajọ naa maa n gbe jade lojoojumọ lati ṣalaye ibi ti nnkan de duro lori ọrọ arun naa kaakiri awọn ipinlẹ gbogbo yika orilẹ-ede yii lo ti sọ eyi di mimọ l’Ọjọbọ, Tọsidee yii.

Ajọ naa kede pe aropọ egbeje o din meji (1,398) lawọn to ṣẹṣẹ lugbadi arun buruku yii kaakiri awọn ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa lorileede yii, ati ilu Abuja.

Latigba ti arun buruku yii ti wọlu Eko, o ti di ọtalerugba eeyan bayii ti arun naa ti pa, aropọ ẹgbẹrun lọna mejidinlogoji lo ti lugbadi ẹ, nigba ti ẹgbẹrun lọna ọgbọn o din diẹ ti gbadun, wọn ti pada sile wọn. Awọn to ku ṣi n gba itọju lọwọ lawọn ibudo iyasọtọ kaakiri ipinlẹ naa.

Leave a Reply