Lasiko tawọn to ji mi gbe sun lọ fọnfọn ni mo sa mọ wọn lọwọ loruganjọ- Atẹrẹ

Stephen Ajagbe, Ilorin

Baale ile ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta, Alhaji Musa Garba Atẹrẹ, tawọn ajinigbe ji gbe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lọna Ogundele si Madi, nijọba ibilẹ Ilọrin West, ti mori bọ ni ibuba awọn to ji i gbe l’Ọjọruu, Wẹsidee, lai san kọbo fun wọn.

Atẹrẹ lawọn ajinigbe tiye wọn n lọ bii mẹfa dena de lasiko toun ati iyawo rẹ n gbe ọmọbinrin rẹ kan to n ṣaisan lọ sileewosan jẹnẹra niluu Ilọrin, fun itọju.

Lẹyin ti wọn gbe e lọ ni wọn kan si mọlẹbi rẹ lati beere fun miliọnu lọna ọgbọn naira.

Nigba to n ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ, ọkunrin tori ko yọ naa ni ibọn lawọn ajinigbe naa na soun atawọn to jọ wa ninu ọkọ lọjọ yii.

O ni wọn so okun nla kan bii eyi ti wọn fi n so maaluu mọ oun lọwọ, wọn si wọ oun tuurutu wọnu igbo lọ.

O ni o ku diẹ kawọn kọja titi marosẹ Oko-Olowo lawọn pade wọn, oun tiẹ kọkọ ro pe fijilante ni wọn, afigba ti wọn wọ oun bọ silẹ ninu ọkọ.

O ni bi wọn ṣe mu oun lọ ni wọn n wo kaakiri tifura-tifura. Odo Moro lawọn gba titi tawọn fi de agbegbe kan ninu igbo, nibi ti ebi ti n pa wọn.

Atẹrẹ tẹsiwaju pe wọn ran meji ninu wọn lati lọọ ra ounjẹ nigboro ilu Oko-Olowo, awọn mẹrin si duro lati maa ṣọ oun.

O ni gbogbo ounjẹ ti wọn fun oun, oun ko jẹ ẹ, omi lasan loun n mu. Wọn kilọ foun pe toun ba gbiyanju lati sa lọ, awọn maa pa oun.

“Lẹyin bii iṣẹju diẹ tawọn to lọọ ra ounjẹ lọ, mẹta lara awọn mẹrin to n ṣọ mi sun lọ, ẹni kẹrin jokoo ti foonu mi, o n tẹ ẹ. Nigba to ya ni ikẹrin naa bẹrẹ si i sun. Bi mo ṣe ri i pe wọn ti sun wọra, ti mo n gbọ bi wọn ṣe n han-an-run, bi mo ṣe ro o lọkan mi pe anfaani ree lati sa lọ niyẹn.”

O ni pẹlu adura toun n fi ọkan gba loun fi dide. Boun ṣe ṣakiyesi pe okun ti wọn fi de oun lẹsẹ ti tu niyẹn. O ni ṣugbọn eyi ti wọn fi de ọwọ oun le gidi gan-an, oun pada gbiyanju, oun si tu u.

O ṣalaye pe aarin igbo loun tọ laarin oru titi toun fi jade si abule kan ti wọn n pe ni Gaa Olobi.

O ni awọn ko san owo kankan fun wọn, lẹyin ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira tawọn n ko lọ si ọsibitu ti wọn gba lọwọ awọn.

Leave a Reply