Nibi ti ọrọ de duro bayii fun gbogbo ọmọ Yoruba, afi ka wa nnkan mi-in ṣe. Ohun ti mo n sọ ni pe afi ka wa ọgbọn mi-in da, bi a ba fẹẹ bọ ninu oko ẹru ti awọn oloṣẹlu ti wọn wa laarin wa ko wa si. Bi ẹ ba ri ẹni kan to ba n tan yin, to n sọ fun yin pe ko si wahala kankan nilẹ Yoruba, ọmọ Yoruba ko si ninu oko ẹru awọn ẹya mi-in ti wọn n ṣejọba ni Naijiria, mo fi Ọlọrun bẹ yin, ẹ ma da tọhun lohun o. Meji ni: bi ko ba jẹ tọhun ko lọgbọn lori, aa jẹ oṣelu tabi ijẹkujẹ lọdọ awọn oloṣelu ti sọ aye rẹ di olukurumuṣu. Nnkan n ṣe wa, ẹni to ba waa ni oun ko mọ, alaimọkan ni. Ipo to yẹ ki Yoruba wa ni Naijiria kọ la wa, awọn ti a si n foju ara-oko ati alaigbọn wo nijọsi ti pada waa di ọba le wa lori, awọn ni wọn si ku ti wọn n paṣẹ waa. Ọrọ naa da bii igba pe epe n ja wa ni. Bẹẹ ọwọ ara wa la fi n ṣe ara wa.
Awa agbalagba ti a jẹ Yoruba ti tẹ, koda, a ti fi atẹ tẹdii. Loju wa bayii, nnkan ti awọn ti wọn jẹ baba fun wa gbe le wa lọwọ, a si sọ ọ di korofo. Eto ẹkọ ni, eto iṣakoso ijọba ni, idagbasoke ọrọ aje ni, gbogbo nnkan wọnyi la fi n jẹ baba ni Naijiria tẹlẹ, gbogbo nnkan yii naa lo si bajẹ loju wa. Nitori pe emi naa jẹ ọkan laarin awọn agbaagba yii, mo ri ohun to n ṣe wa daadaa. Ohun to n pa wa ku naa ni imọtara-ẹni-nikan, tabi riro pe awa nikan la gbọn ju, ohun to si fa ainiṣọkan laarin wa niyẹn. Gbogbo ẹnikẹni to ba jokoo sibi kan, to n ro pe oun nikan loun lọgbọn ju laarin awọn ẹgbẹ oun, ati pe gbogbo ohun ti oun ba gbe kalẹ lawọn to ku gbọdọ tẹle, imọtara-ẹni nikan ni, ohun ti Yoruba si sọ nipa iwa emi-nikan-ni-mo-gbọn-tan yii ko daa. Yoruba ni, ẹni to gbọn, to lẹni kan ko gbọn, oun ni baba were, oun ni baba digbolugi.
Ohun ti Yoruba ṣe sọ bẹẹ fun awọn ti wọn n ro ara wọn si ọlọgbọn aye yii ni pe ko si ẹni kan ti i gbọn tan, ọmọde gbọn, agba gbọn, la fi da ilẹ Ifẹ; bẹẹ ni ọwọ ọmọde ko to pẹpẹ, ti agbalagba ko wọ kengbe, ẹni kan ki i gbọn tan, nitori ibi ti ọgbọn ẹni kan ba pin si, ibẹ ni tẹlomi-in yoo ti bẹrẹ, Ọlọrun to da gbogbo wa, ko fi idi ọgbọn han ẹni kan. Bi ẹni kan ba wa laarin yin, ti Ọlọrun gba adura rẹ lojiji, to di olowo, kia lo maa sọ ara rẹ di alaṣẹ, ti aa maa paṣẹ hauhau, ati ọlọgbọn ati onimọ, aa fẹ ki gbogbo wọn wa labẹ oun. Bẹẹ oun ko lọgbọn, ko nimọ paapaa, owo lo ni. Ohun to buru ni pe ko ni i fẹ koun sọrọ kẹni kan ta ko oun, nitori loju tirẹ, olowo nikan ni baba. Bi ẹni kan ti ko jẹ kinni kan lanaa ba gbe igba oṣelu, ti wọn jaja fi i ṣe alaga kansu, tabi to di gomina laarin yin, loju yin yii naa, kia ni yoo ya ara rẹ sọtọ.
Ki i ṣe pe yoo ya ara rẹ sọtọ nikan ni o, yoo sọ ara rẹ di baba le gbogbo ẹni to ku lori, titi dori awọn ti wọn dibo yan an, ati awọn ti wọn ronu lati fa a kalẹ. Agaga ẹni to ba di gomina tabi aṣofin, wahala ti de niyẹn, bi ọlọpaa ko ba tọ si i, yoo fi ọna awuruju ko ọlọpaa meji tabi ju bẹẹ lọ yi ara rẹ ka, yoo si bẹrẹ si i ṣe bii ẹni pe oun ni baba fun gbogbo yin. Bẹẹ korofo ni o, ko jẹ kinni kan, ọgbọn ẹyo kan bayii ko si si lori rẹ. Ohun to fa a ti kaluku fi n du ipo fun ara rẹ niyi. Awọn oloṣelu wa ko tori pe wọn yoo ṣe ilu tabi iran Yoruba loore maa du ipo yii, nitori ki wọn le lowo ati ọla ati agbara ju ara yooku lọ ni. Ọpọ olowo ilẹ wa ko nifẹẹ awọn eeyan rẹ, ki wọn lowo nidii okoowo tabi nidii iṣe kọngila, ki wọn si maa fi owo yii rẹ ara yooku jẹ ni. Nigba ti ẹ ba tu idi eyi wo, imọtara-ẹni-nikan naa ni. Eleyii lo si ba gbogbo nnkan jẹ fun wa.
O ba nnkan jẹ fun wa nitori pe iwa imọtara-ẹni-nikan yii lo bi afemi-afemi. Ko sohun ti ẹni to mọ ti ara rẹ nikan n wa kiri ju ki gbogbo aye maa sọ pe afi oun, afi oun lọ. Nibi to ti n wa eleyii kiri ni igberaga yoo ti wọle, nitori yoo ro pe oun lolori aye ni; ọkanjuwa yoo wọ ọ nitori ko ni i fẹ ki ẹnikẹni ni nnkan ju oun lọ, gbogbo ohun ti awọn mi-in ba ni ni yoo fẹ ko jẹ tirẹ. Awọn nnkan ti mo n sọ yii ni o jẹ ki awa agbaagba ilẹ Yoruba asiko yii gbọ ara wa ye. Awọn ti wọn fẹ ti ilu ati ti iran Yoruba denudenu ko to nnkan, kidaa awọn ti wọn n forukọ Yoruba jẹun lo pọ lọ jaburata. Wọn n fi orukọ Yoruba jẹun, bẹẹ ni wọn n ba iran Yoruba jẹ. Bi ọrọ oṣelu ba ti de, wọn aa jade, wọn aa lawọn laṣaaju Yoruba, awọn ni gbogbo ọmọ Yoruba n fori balẹ fun, awọn ni olori wọn. Bẹẹ irọ ni o: ẹni to n sọrọ yii, pẹlu awọn aṣalàjẹ bii meji mẹta kan ni wọn ko ara wọn jọ, ti wọn n tu araalu jẹ.
Idi niyi ti aṣaaju Yoruba fi pọ kaakiri, nitori ọgbọn atijẹ lasan, imọtara-ẹni-nikan lasan, afemi-afemi lasan, ni gbogbo wọn n ba kiri. Ẹ wo ẹgbẹ ọmọ Yoruba ti wọn gbe kalẹ laipẹ yii, Yoruba World Congress, ẹgbẹ ti wọn fi Ọjọgbọn Banji Akintoye ṣe olori rẹ, loju wa nibi, lai ti i pe ọdun kan ti ẹgbẹ naa dide, ni wọn lu ẹgbẹ naa fọ pata. Ki i kuku u ṣe Fulani tabi Buhari lo lu u fọ, bi awọn yii ba tilẹ lọwọ si iṣubu ẹgbẹ naa, sibẹ awọn Yoruba wa ni wọn lo lati fọ ọ. Awọn ti wọn jọ bẹrẹ ẹgbẹ naa bii Tọla (Adeniyi), Amos (Akingba), ati awọn diẹ kan ti wọn ko tilẹ lorukọ nibi kan ni wọn ṣaaju, ti wọn lu ẹgbẹ naa fọ. Ẹgbẹ ti gbogbo Yoruba ti n gbọkan tẹ, ẹgbẹ ti wọn n ro pe yoo ṣe oore fun iran wa, awọn ti wọn gbe e soke naa ni wọn lo lati fa a walẹ kia.
Ọtọ ni Afẹnifẹre ti Baba (Adebajo). Nibi lawọn agba bii Faṣọranti, Fẹmi (Okurounmu), Olu (Falae), Ṣupọ (Sọnibare) ati Yinka (Odumakin) pẹlu awọn mi-in wa. Igba ti ina Afẹnifẹre n jo, awọn Bọla (Tinubu), dide, wọn lu u fọ. Nidii eyi, ọtọ ni Afẹnifẹre tiwọn. Lọdọ wọn lawọn bii Bisi (Akande), Ṣẹgun (Ọṣọba), Biyi (Durojaye) atawọn mi-in wa. Bi kinni kan ba waa ṣẹlẹ, ti Afẹnifẹre tawọn Yinka ba ni awọn o gba, kinni naa ko tẹ Yoruba lọrun, awọn Afẹnifẹre ti Bọla aa ko ero lẹyin, wọn n lọ sọdọ awọn Buhari atawọn Fulani to n mu wa sin niyẹn, wọn aa ni ohun ti wọn n ṣe yẹn gan-an ni ki wọn mura si i, nitori gbogbo Yoruba lo wa lẹyin wọn. Nibẹ ni nnkan ti maa daru, nitori ko ni i sẹni to mọ ojulowo Afẹnifẹre. Bo ṣe ri ninu Ẹgbẹ Igbimọ Agba (Yoruba Council of Elders) naa ree, wọn ti lu ẹgbe naa fọ mọ ara wọn lori.
Ẹgbẹ OPC to wa nilẹ yii to meji mẹta, ọtọ ni ti Gani Adams, ọtọ ni tawọn ọmọlẹyin Fasehun, awọn mi-in si tun wa ti wọn ko ara wọn jọ. Ohun to fa a to fi jẹ ẹgbẹ oriṣiiriṣii to wa nilẹ Yoruba loni-in yii le ni irinwo, Yoruba ni gbogbo wọn si ni awọn n ja fun, bẹẹ ni wọn ko ri ija kan yanju, wọn ko si ri idagbasoke kan mu wa ba wa. Ko sohun to fa a ju pe ọpọ awọn eeyan naa n fi orukọ Yoruba jẹun lasan ni. Wọn n lo Yoruba lati fi wọn gba nnkan l’Abuja: wọn n gba ipo, wọn n gba owo, wọn si n gba agbara (si apo ara wọn nikan ni o!), wọn ko si fi kinni naa ṣe anfaani fun iran wa, nitori wọn n ta wa fawọn ẹya mi-in ni.
Nibi ti ọrọ wa de yii, ki la oo ṣe. O ti han si mi pe ti a ba gboju le ti awa agbaagba ilẹ Yoruba nikan, ọrọ Yoruba ko ni i yanju, kaka bẹẹ, awọn agbalagba yii yoo ti ti Yoruba sinu ọfin ni. Ootọ ọrọ ko ṣaa ni i sọ pe ka ma sọ oun. Nidii eyi, ọrọ naa ti yi kan ẹyin ọdọ aarin wa, ẹyin ọdọ ọmọ Yoruba, ẹyin ti ẹ wa lati bii ọgbọn ọdun dori aadọta, ẹyin ni iṣe wa lọwọ yin lati ko iran Yoruba yọ. Ki lẹ fẹẹ ṣe, bawo ni ẹ o si ti ṣe e? Ẹ jẹ ka pade lọsẹ to n bọ.