Lẹyin ọjọ mẹrin ti wọn ni ẹmi airi le awọn akẹkọọ jade nileewe kan ni Kwara, wọn ti pada sẹnu ẹkọ

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni wọn ṣi ile ẹkọ girama (St Chaire Anglican Girls Grammar School) to wa niluu Ọfa, nipinlẹ Kwara, pada lẹyin ọjọ mẹrin ti wọn ni ẹmi airi kan le wọn jade nile ẹkọ ọhun.

ALAROYE gbọ pe, ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ to kọja, ni awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa pariwo pe awọn n gbọ ohun ajoji, ti o si n ṣẹru ba wọn lọpọlọpọ, eyi lo ṣokunfa bi wọn ṣe ti ile-ẹkọ naa pa.

Sugbọn ni bayii, awọn alaṣẹ ile-ẹkọ ọhun ti ṣe ipade pajawiri, wọn si ti fẹnu ko pe ki ile-ẹkọ naa yoo di ṣiṣi pada ni ọjọ Aje Mọnde ọsẹ yii.

Ninu atẹjade ti ile-ẹkọ girama naa fi sita ni wọn ti sọ pe ki awọn alaṣẹ ile-ẹkọ, to fi mọ awọn olukọ, ki wọn gba adura ọlọjọ mẹta pẹlu aawẹ, ki awọn ẹmi airi naa o le poora.

Adura naa bẹrẹ ni ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nigba ti Bishop Rev Dr Oluṣọla Akanbi lewaju nibi adura ọhun. Wọn ti waa ni ko si ewu mọ, ki eto ẹkọ gbera sọ pada ni ẹyẹ-o-ṣọka.

Leave a Reply