Lẹyin ti Amọs fi okoowo sogun-dogoji lu awọn eeyan ni jibiti l’Ekoo lo sa lọ si Sokoto

Faith Adebọla, Eko

Amos Ọmọlade Sewanu lorukọ ọkunrin tẹ ẹ n wo fọto ẹ yii, ṣugbọn Spark ni inagijẹ tawọn eeyan mọ ọn si, ọmọ agbegbe Badagry, niluu Eko ni, ibẹ lo ti fi okoowo sogun-dogoji kan lu awọn eeyan ni jibiti owo rẹpẹtẹ ko too fere ge e, o sa lọ si ipinlẹ Sokoto, ṣugbọn ọwọ ajọ EFCC ti ba a.

Ba a ṣe gbọ, wọn niṣe lọkunrin naa da okoowo ori atẹ ayelujara kan silẹ to pe ni Inks Nation Ponzi Scheme, nibẹ lo ti n sọ pe kawọn eeyan maa ko owo wọn wa, pe ti wọn ba fi ẹgbẹrun mẹwaa naira to kere ju sibẹ, wọn maa fi gba ẹgbẹrun ogun laarin wakati mẹta pere.

Ọlọrun lo mọ bo ṣe n ṣe e, wọn nigba to bẹrẹ kinni ọhun, loootọ lawọn eeyan to fowo sibẹ ri ere ilọpo meji gba, eyi lo mu ko gbajumọ bii iṣana ẹlẹẹta nidii okoowo sogun-dogoji yii, tawọn olowo ti wọn si n rọ ẹgbẹgbẹrun naira sori okoowo ọhun.

Wọn tun lafurasi ọdaran yii da owo ayelujara tiẹ silẹ, o porukọ ẹ ni “Pinkcoin” o si maa n pin kaadi arumọjẹ kan fun wọn to pe ni “Pink Card”, o loun ni kaadi ti wọn maa maa fi gba owo wọn pẹlu ele, owo pinkcoin rẹpẹtẹ ti wọn ba gba naa ni wọn maa lọọ ṣẹ si naira tabi dọla, ni wọn aa ba dolowo yalumọ.

Ṣe wọn ni ẹni n wa ifa n wa ofo, ko pẹ ti ileeṣẹ Inks Nation rẹ ati Pincoin ati Pink Card ọhun fi la’na, lokoowo ba lukudeeti, lariwo ba ta.

Alukoro ajọ EFCC to jẹ ka gbọ nipa iṣẹlẹ yii, Wilson Uwajuren, ni owo awọn ẹni ẹlẹni to wọgbo sapo afurasi ọdaran naa ju miliọnu mejilelọgbọn naira lọ.

Ọmọlade ko ṣe meni ṣe meji, niṣe lo di ẹru rẹ paapaapaa ki awọn olowo too ka a mọle, o ba ẹsẹ rẹ sọrọ lai dagbere fẹnikan, lo ba dawati.

Gbogbo isapa awọn agbofinro lati ri i lo ja si pabo, ko sẹni to mọ pe o ti kuro lagbegbe Eko, koda, ko duro nilẹ Yoruba paapaa, ṣugbọn awọn ọtẹlẹmuyẹ tọpasẹ rẹ, wọn pin fọto rẹ kaakiri ọdọ awọn agbofinro, lọwọ ba tẹ jagunlabi niluu Ṣokoto l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, wọn si fi pampẹ ofin mu un.

Uwajuren ni iṣẹ iwadii ṣi n tẹsiwaju, wọn lo ti jẹwọ pe loootọ loun ṣe okoowo jibiti ọhun, ki wọn ṣe oun jẹẹjẹ.

Wọn ni tiṣẹ iwadii ba ti pari, wọn maa foju ẹ bale-ẹjọ ni.

Leave a Reply