Lẹyin ti wọn gba miliọnu meji Naira, awọn ajinigbe tu Sulia silẹ n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Sulia, ọmọ gbajumọ olori nni, Alaaja Kẹhinde Ejide, ti awọn ajinigbe ji gbe nile rẹ lagbegbe Oko-Olowo, niluu Ilọrin, ti gbominira bayii lẹyin tawọn ajinigbe gba miliọnu meji Naira owo itusilẹ.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹta idaji ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni awọn ajinigbe naa ya bo ile rẹ ni agbegbe ọhun. Ọkọ rẹ ni wọn fẹ ji gbe, ṣugbọn nigba ti wọn ko ri ọkọ ni wọn ba gbe iyawo, iyẹn Sulia lọ.

Wọn ni ko pẹ pupọ ti wọn gbe e tan ni wọn pe mọlẹbi, ti wọn si n beere fun miliọnu meji Naira owo itusilẹ, awọn mọlẹbi da miliọnu meji jọ lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ni wọn gbe owo naa lọ, ti awọn ajinigbe ọhun si tu Sulia, silẹ layọ ati alaafia.

Awọn mọlẹbi ko fi ọrọ naa to ọlọpaa tabi ẹṣọ alaabo kankan leti tori pe wọn ni wọn o gbọdọ sọ fun ọlọpaa.

Leave a Reply