L’Oṣogbo, Mariam dawati, lawọn obi rẹ ba fẹsun kan pasitọ to n ṣetusilẹ fun un

Florence Babaṣọla

Idile ọmọdebinrin kan, Mariam Rauf, ti wọ ṣokoto kan naa pẹlu pasitọ ijọ wọn latari bi ọmọ naa se dede dawati latinu oṣu kẹta, ọdun yii, ti ko si sẹnikankan to mọ ibi to wa.

Mariam, ọmọ ọdun mejidinlogun, la gbọ pe lati ọdun 2019 lo ti n sun inu ṣọọṣi, nibi ti Pasitọ Ọla John ti n ṣetusilẹ fun un nitori bo ṣe maa n tọ sile (bed wetting).

A gbọ pe ọrẹ iya Mariam kan lo mu un lọ si ṣọọṣi naa, ti pasitọ si gba wọn niyanju pe ki wọn jẹ ko maa sun inu ṣọọṣi titi ti ogun aye rẹ yoo fi ṣẹ patapata, latigba naa ni ṣọọṣi ti di ile keji fun un.

Lojoojumọ, to ba ti ji laaarọ, yoo lọ sile wọn lọ mura fun ileewe, to ba ti kuro nileewe, aa kọri sibi to ti n kọṣẹ hiadirẹsa, to ba ti ṣiwọ iṣẹ, ṣọọṣi ni yoo fabọ si.

Ṣugbọn bo ṣe lọ sile lọọ mura ileewe laaarọ ọjọ Mọnde ọhun, iyẹn ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun yii, to si dagbere ileewe, ni wọn ko ti gburoo rẹ mọ, wọn fi to awọn ọlọpaa leti, pabo lo ja si.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lori iṣẹlẹ naa, iya Mariam, Bukọla Ayẹni ṣalaye pe nigba ti itọ to n tọ sile ti fẹẹ di itiju loun fi ọrọ naa lọ ọrẹ oun kan, ẹni to gba oun niyanju lati lọ sọdọ pasitọ naa.

O ni, “Nigba ti mo de ọdọ Pasitọ Ọla John, mo ṣalaye ohun ti mo ba wa, wọn si gba mi nimọran pe ṣe ni ki n jẹ ko wa maa sun sinu ṣọọṣi ki ogun naa le ṣẹ patapata, niwọn igba to si jẹ pe adugbo ti a n gbe ni Arogunmaṣẹ naa ni ṣọọṣi wọn wa, mo gba.

“To ba ti sun mọju ninu ṣọọṣi, yoo wa sile wa jẹun laaarọ, yoo si mura ileewe, to ba ti kuro nibi to ti n kọṣẹ aṣerunlọṣọọ nirọlẹ, ṣọọsi ni yoo pada si.

“Nibẹrẹ ọdun yii, ọkọ mi sọ pe niwọn igba ti Mariam o ti tọ sile mọ, ki n jẹ ko pada sile. Mo lọọ ṣalaye fun pasitọ, ṣugbọn wọn ni ki n jẹ ko ṣi wa ninu ṣọọṣi. Ẹẹmeji to sun inu ile, ṣe lo wọnu ẹmi laarin oru, bi a tun ṣe da a pada si ṣọọṣi niyẹn.

“O mura ileewe rẹ, Baptist Girls Secondary School, Oṣogbo, laaarọ ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun yii, o si jade ninu ile, latigba naa ni n ko ti gburoo ọmọ mi mọ. A ti wa a kaakiri ipinlẹ Ọṣun, a ko ri i.

“Ohun to waa jọ mi loju ni pe, bi a ṣe n wa a to, Pasitọ Ọla John o kan tiẹ fitara han rara, ko ṣe bii ẹni pe ọdọ rẹ ni ọmọ yẹn n gbe ju, awa nikan la n sare kaakiri lori ẹ. Mo ti lọọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa agbegbe Oke-Baalẹ leti, sibẹ, n ko gbọ nnkan kan latọdọ wọn”

Nigba ti Pasitọ Ọla n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, o ni loootọ ni Mariam maa n sun inu ṣọọṣi oun lalaalẹ, ṣugbọn oun ko mọ nnkan kan nipa bo ṣe deede dawati.

O ni irọ patapata ni pe oun ko kọbiara si wiwa ọmọ naa, o ni lara igbiyanju oun loun fi pade ọrẹ rẹ kan to sọ fun oun pe Ilẹ Yibo ni Mariam wa nibi to ti n ta agunmu (herbal products) bayii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe ki a fun oun lasiko diẹ lati le fidi iṣẹlẹ naa mulẹ nigba ti a pe e.

 

Leave a Reply