L’Ogun, Dapọ Abiọdun ni yoo dije sipo gomina lẹẹkeji lorukọ ẹgbẹ APC

Gbenga Adebọla, Abẹokuta

Ifa ti fọre fun Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, lati dupo gomina ipinlẹ naa ninu eto idibo gbogbogboo to n bọ lọdun 2023. Ọkunrin naa lo jawe olubori ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ All Progressives Congress (APC), eyi to waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un yii ninu ọgba papa iṣere Moshood Abiọla Stadium, Kutọ, l’Abẹokuta. Ọgbẹni Wale Ohu lo dari rẹ.
Awọn oludije mẹfa ni wọn kopa ninu eto naa, ṣugbọn meji ninu wọn, Adekunle Akinlade ati Biyi Ọtẹgbẹyẹ, ti kọkọ fi aidunnu wọn han si yiyan ti wọn yan Ohu lati ṣe alaga igbimọ to maa dari eto idibo abẹle ọhun, latari bi wọn ṣe fẹsun kan an pe awọn eto idibo abẹle to kọja lawọn wọọdu, ijọba ibilẹ ati ipinlẹ, ẹni yii lo ṣamojuto rẹ, awuyewuye rẹpẹtẹ lo n tidi ẹ yọ, oju to si maa ba ni kalẹ ki i taarọ ṣe’pin.
Eyi lo mu wọn kọ lẹta ẹsun jan-an-ran jan-an-ran kan si Alaga apapọ ẹgbẹ APC, Abdullahi Adamu, wọn ni ko paarọ alaga naa, tori awọn ko nigbagbọ ninu ẹ rara.
Wọn tun tọka si awọn aleebu kan ninu akọsilẹ orukọ awọn aṣoju ti wọn fẹẹ dibo naa.
Ṣugbọn lopin eto ọhun, Wale Ohu kede pe ibo ẹgbẹrun kan ati mejidinlaaadọsan-an (1,168) ni Dapọ Abiọdun ni, o si fẹyin awọn marun-un yooku ti wọn jọọ dije janlẹ gidi.
Alaga naa tun kede pe aropọ ẹgbẹrun kan o le aadọsan-an (1,170) ni wọn di, meji ninu ibo naa ko ṣee ka, gbogbo iyoku pata si jẹ ti Gomina Abiọdun.
Ninu ọrọ idupẹ rẹ, Abiọdun ṣeleri pe niṣe loun maa lo anfaani yiyan ti wọn yan oun yii lati tubọ jara mọṣẹ nipinlẹ Ogun, o ni iyan maa di atungun, ọbẹ si maa di atunse lori ipese awọn ohun amayedẹrun ati igbayegbadun araalu nipinlẹ naa.

Leave a Reply