Makinde forukọ awọn kọmiṣanna tuntun ranṣẹ sawọn aṣofin l’Ọyọọ

Faith Adebọla

Lẹyin to juwe ile fun awọn kọmiṣanna mẹtadinlogun ati olori awọn oṣiṣẹ, Oloye Bisi Ilaka, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti fi orukọ awọn kọmiṣanna tuntun ti yoo maa baa sakoso ijọba nipinlẹ naa ranṣẹ sawọn aṣofin.

ALAROYE gbọ pe meje ninu awọn mẹtadinlogun ọhun lo jẹ awọn to ti ba a ṣiṣẹ tẹlẹ. Awọn naa ni: Ṣiju Lawal, Oyelọwọ Oyewọ, Akinọla Ojo, Bayọ Lawal, Ṣeun Ashamu ati Faosat Oni. Gbogbo awọn eeyan wọnyi la gbọ pe o ṣee ṣe ki wọn pada si ipo ti wọn ti di mu tẹlẹ ki gomina too tu wọn ka.

Asiko ti awọn aṣofin yoo jokoo, ti wọn yoo si buwọ lu iyansipo wọn, ti awọn eeyan naa yoo si bẹrẹ iṣẹ ni rẹbutu lawọn araalu n duro de.

Leave a Reply