Meji lara awọn oṣiṣẹ Gomina Oyetọla ti lugbadi arun Korona

Florence Babaṣọla

 

 

Meji lara awọn to sun mọ Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ti lugbadi arun koronafairọọsi bayii.

Ninu atẹjade kan ti Kọmisanna feto iroyin ati ilanilọyẹ, Funkẹ Ẹgbẹmọde, fi sita lo ti ṣalaye pe, lẹyin ti gomina paṣẹ pe ki gbogbo awọn kọmisanna atawọn oludamọran pataki fun un lọọ ṣe ayẹwo naa lo di mimọ pe meji lara wọn ti ni i.

ALAROYE beere lọwọ Kọmisanna fọrọ ilera, Dokita Rafiu Isamọtu, lati mọ boya kọmisanna lawọn ti wọn ni i, tabi oludamọran pataki, ṣugbọn Isamọtu ni ofin iṣẹ awọn ko faaye rẹ silẹ lati ba wa sọ iru ẹ, niwọn igba ti awọn tọrọ kan ko ti sọ pe kawọn polongo.

Ni ti Ẹgbẹmọde, o ni “Lara ọna lati dena itankalẹ arun Korona nipinlẹ Ọṣun, Gomina Gboyega Oyetọla ti kan an nipa fun gbogbo awọn kọmisanna rẹ atawọn oludamọran pataki lati lọọ ṣe ayẹwo ara wọn.

“Bẹẹ lo tun paṣẹ pe ki gbogbo awọn dẹrẹba atawọn oṣiṣẹ inu ilegbee gomina yọnda ara wọn fun ayẹwo Korona ni kiakia. Gomina lo kọkọ fi apẹẹrẹ rere lelẹ nipa ṣiṣayẹwo ara rẹ, idi niyẹn to fi sọ pe ki awọn abẹṣinkawọ rẹ naa lọ fun un, to si tun rọ awọn araalu pe kawọn naa lọ fun ayẹwo ọhun, ki wọn le tete mọ boya wọn ti lugbadi rẹ tabi bẹẹ kọ.

“Nibi ayẹwo lo ti di mimọ pe awọn meji ti ni i, awọn mejeeji si ti wa nigbele bayii, wọn n lo oogun wọn bo ṣe yẹ, laipẹ ni wọn yoo tun lọ fun ayẹwo lẹẹkeji lati mọ boya arun naa ti kuro lara wọn”

O sọ siwaju pe teeyan ba tete mọ nipa arun yii, yoo rọrun lati tete ṣetọju ẹ, ti yoo si dena itankalẹ rẹ laarin mọlẹbi tabi nibi iṣẹ.

Leave a Reply