Faith Adebọla
Ẹgbẹ awọn darandaran onimaaluu ilẹ Hausa, Miyetti Allah Cattle Breeders’ Association of Nigeria (MACBAN), ti rọ gbogbo awọn Fulani darandaran to wa lawọn ipinlẹ mẹtadinlogun iha Guusu ilẹ wa lati fi agbegbe naa silẹ kia.
Alaga ẹgbẹ naa, Sadiq Ibrahim Ahmed, lo parọwa naa fawọn darandaran ọmọ ẹgbẹ rẹ lọjọ Abamẹta, Satide yii, o ni ipinnu tawọn gomina ipinlẹ mẹtadinlogun Guusu ilẹ wa ṣe lati fofin de fifi maaluu jẹko ni gbangba lagbegbe wọn ti fihan pe wọn o nifẹẹ awọn Fulani, ko si sohun to yẹ ju ki wọn kuro nibi ti wọn o ti nifẹẹ wọn lọ.
O ni: “Ọrọ yii o le, orileede yii maa pin ni. Awọn adari o fẹran araalu mọ. Nigba ti wọn ba lawọn fofin de awọn eeyan kan pe ki wọn ma fi maaluu jẹko ni gbangba, ki lo waa tun ku? Kawọn Fulani kuro nibẹ ni o, tori kaluku lo ti n paṣẹ to ba wu u bayii.
Awọn gomina Guusu le paṣẹ to wu wọn, iyẹn o ṣe nnkan kan, ẹ jẹ ki wọn ṣe bo ti wu wọn. To ba wu awọn gomina Ariwa, awọn naa le paṣẹ pawọn o fẹ fifi maaluu jẹko ni gbangba pẹlu.
“Ko sẹjọ lọwọ wọn, digẹrẹwu l’Aarẹ ta a ni, o kan wa nibẹ ni, ko mọ ohun to n ṣe. Ẹnu ẹ o tọrọ mọ, iyẹn lo fa a to jẹ pe kaluku kan n ṣofin bo ṣe wu u, wọn si n paṣẹ bo ṣe wu wọn lorileede yii. Orileede yii ti n pinya lọ lẹ n ri yẹn o, nigba tawọn kan ba le ko ara wọn jọ sibi kan, ki wọn si lawọn paṣẹ to ta ko ofin ilẹ wa, ki nijọba apapọ n wo, nibo ni wọn wa?
Ọkunrin naa ni dipo kawọn gomina Guusu wọnyi gbaju mọ ipenija awọn ọdaran ti wọn n fojoojumọ dana sun dukia lagbegbe wọn, ọrọ ti Fulani darandaran ni wọn n ran mọnu.”
O ni ojuutu si iṣoro orileede yii ni ki Aarẹ Buhari bọ sẹgbẹẹ kan bayii, kawọn eeyan le fori kori, ki wọn si ṣeto yiyan aarẹ to maa mu ayipada rere wa lọdun 2023, ki wọn yan aṣaaju to maa mọ ohun to n ṣe, to si maa kaju ẹ.
“Naijiria gbọdọ yan aṣaaju to lapẹẹrẹ rere, to si ṣetan lati fi ẹmi ẹ rubọ fawọn to n ṣakoso le lori.”