Mo maa dupo aarẹ lọdun 2023-Saraki

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Aarẹ ileegbimọ aṣofin agba tẹlẹ lorileede Naijiria, Bukola Saraki, ti fi erongba rẹ lati kede pe oun yoo dije dupo aarẹ lasiko idibo ọdun 2023.

ALAROYE gbọ pe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni Saraki lọọ ṣabẹwo si Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom, niluu Makurdi, pẹlu gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ, Idris Wada, alaga apapọ ẹgbẹ PDP tẹlẹ, Kawu Baraje, Sẹnetọ Suleiman Adokwe, ati Alaga ipolongo ibo fun Saraki Ọjọgbọn Iyorwuese Hagher. Ibẹ lo ti kede erongba rẹ lati dije dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.

Ninu ọrọ Ortom, o ni ẹgbẹ oṣelu PDP ni mesaya bayii ti yoo gba orileede Naijiria silẹ lọwọ ẹgbẹ to n ṣejọba lọwọ, iyẹn ẹgbẹ oṣelu APC. O tẹsiwaju pe Saraki ni ẹni akọkọ to wa lati ẹkun Aarin Gbungbun orile-ede yii ti yoo kede erongba rẹ lati dupo aarẹ lọdun 2023.

Bakan naa ni Saraki sọrọ lori opo abẹyẹfo rẹ (Twitter), pe oun ti setan lati ṣiṣẹ pẹlu gbogbo awọn eekan inu ẹgbẹ oṣelu PDP, Aarin Gbungbun Ariwa orile-ede yii lati mu idagbasoke ti ko lẹgbẹ ba ẹkun naa. O waa dupẹ lọwọ wọn fun bi wọn ṣe gba a lalejo.

Leave a Reply