Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Mọto Toyota Camry dudu kan to ni nọmba EKY 730 AT, la gbọ pe o fori sọ igi ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, loju ọna Ibodi, niluu Ileṣa si Ifẹ.
Gẹgẹ bi Alukoro ajọ ẹṣọ-oju popo nipinlẹ Ọṣun, Agnes Ogungbemi, ṣalaye pe o ṣee ṣe ko jẹ pe ilẹ lo yọ mọto naa, to si ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun.
Eeyan mẹrin; ọkunrin mẹta ati obinrin kan, lo wa ninu mọto naa, loju-ẹsẹ si ni ọkunrin kan gbẹmi-in mi nibẹ, nigba ti awọn mẹta fara pa yanna-yanna.
Ogungbemi sọ pe awọn ọlọpaa agbegbe Oṣu ti gbe ẹni to ku atawọn mẹta to fara pa lọ sileewosan Wesley Guild Hospital, niluu Ileṣa.
O ni apo kan to kun fun ounjẹ ti awọn ba ninu ọkọ naa ti wa lọfiisi awọn niluu Ileṣa.