Nibi ti Adamu atọrẹ ẹ ti n jale loju popo lawọn ọlọpaa ka wọn mọ l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Adamu Nura, ẹni ogun ọdun, ati ọrẹ kan, AbdulKareem Hamzat, ẹni ọdun mẹrinlelogun, ti n ṣalaye ara wọn fawọn ọtẹlẹmuyẹ lahaamọ ọlọpaa ti wọn fi wọn si ni Panti. Nibi ti wọn ti n fi ibọn ja awọn onimọto ati ero ọkọ lole lawọn agbofinro ka wọn mọ l’Ekoo.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Ọgbẹni Olumuyiwa Adejọbi, to fiṣẹlẹ yii to ALAROYE leti sọ pe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, lọwọ ba awọn afurasi adigunjale mejeeji ọhun.

Nigba ti wọn mu wọn, Hamzat ni adugbo NEPA Road, ni Alaba Rago, l’Ọjọọ, loun n gbe, nigba ti ọrẹ ẹ, Adamu, n gbe adugbo Karabosowa, ni Ọjọọ, kan naa.

Awọn ero ọkọ kan ti wọn ja lole nitosi ọja iṣu TIV Yam Market, nitosi marosẹ Eko si Badagry, ni wọn kegbajare sawọn ọlọpaa to n kọja lọ ninu mọto wọn, lawọn yẹn ba ṣẹri pada lati tọpasẹ wọn, wọn si ri wọn lọọọkan ti wọn tun n ṣiṣẹẹbi wọn nidii ọkọ mi-in lasiko sun-kẹrẹ fa-kẹrẹ to ṣẹlẹ lọna naa.

Wọn ni bawọn gbewiri mejeeji yii ṣe ri awọn agbofinro ni wọn ya danu, wọn fẹẹ sa lọ, ṣugbọn ọwọ tẹ wọn.

Ọbẹ aṣooro meji, ohun eelo ti wọn fi n ge irin, ada kan, rọba ti wọn fi n ta oko fẹyẹ (catapult) ati egboogi oloro ti wọn fura pe igbo ni, l’Adejọbi ni wọn ba lara awọn mejeeji nigba tọwọ ba wọn.

Wọn tun ri foonu ti wọn fura si pe niṣe ni wọn jale rẹ lọwọ awọn ero, ati owo.

Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, ti paṣẹ pe kawọn mejeeji maa jaye ori wọn lọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, wọn yoo si balẹ sile-ẹjọ to ba ya.

Leave a Reply