Nibi ti wọn ti n sa fun ọlọpaa, odo gbe ọlọkada meji lọ n’Igbara-Odo l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Awọn eeyan ilu Igbara-Odo Ekiti, nijọba ibilẹ Guusu Ekiti, ti wa ninu ọfọ ati ẹkun bayii pẹlu bi odo nla kan to wa niluu naa ṣe gbe awọn ọlọkada meji kan lọ ni ilu naa.

Gẹgẹ bi awọn eeyan ilu naa tọrọ ọhun ṣoju wọn ṣe sọ, awọn ọlọkada meji naa ti orukọ wọn njẹ Ojo Okonta ati ọrẹ timọ-timọ rẹ, Ṣẹgun Adetoun, ti wọn jẹ gbaju-gbaja ọlọkada niluu naa ni wọn lọ si eti odo yii lọjọ Iṣẹgun, Tuside, lati fọ ọkada wọn lẹyin ti wọn pari iṣẹ lọjọ naa.

Wọn ṣalaye pe ni kete ti wọn de eti odo naa ni awọn ọlọpaa wa sibẹ lati ṣawari awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ti wọn n lo eti odo naa lati ṣe ipade wọn.

Wọn fi kun un pe ni kete ti Okonta ati ọrẹ rẹ foju gan-an-ni awọn ọlọpaa wọnyi ni wọn fi ọkada wọn silẹ, ti wọn si bẹ sinu odo naa, ki awọn ọlọpaa ma le mun wọn.

Okonta ati ọrẹ rẹ ti ọjọ ori wọn ko ju bii ọgbọn ọdun lọ, ni wọn ti maa n lo eti odo naa lati ṣere, ti wọn aa si fọ ọkada wọn ni kete ti wọn ba ti pari iṣẹ oojọ wọn.

Ẹnikan to n gbe ni ilu naa sọ pe odo nla naa ṣadeede kun soke ni kete ti ojo nla kan rọ lọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Oku awọn mejeeji ni wọn pada ri ni odo nla kan ni ilu Ọwena, to wa nijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ, nipinlẹ Ondo, ni kutukutu ọjọ Tọsidee.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ọlọpa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe odo gbe eeyan meji lọ nigba ti wọn fẹẹ luwẹẹ ninu odo naa ni kete ti ojo nla kan ṣẹṣẹ rọ da.

Abutu sọ pe wọn ri oku awọn mejeeji ni Ọwena, nipinlẹ Ondo, wọn si ti jọwọ oku wọn fun awọn mọlẹbi wọn.

Bakan naa ni ẹnikan to n gbe ilu naa ti ko fẹ ka darukọ oun sọ pe awọn ọdọ kan ati awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni ilu naa ti sọ eti odo ọhun di ibi ti wọn ti n ṣe ipade wọn tabi ti wọn ti n gba awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun sinu ẹgbẹ wọn, ti wọn si tun maa n mu igbo nibẹ.

O ṣalaye pe gbogbo ipa ti awọn eeyan ilu naa ti sa lati dẹkun lilo eti odo naa fun iṣẹ ibi lo ja si pabo.

O fi kun un pe awọn meji ti odo naa gbe lọ bẹ sinu rẹ ni kete ti wọn ri awọn ọlọpaa, odo naa si gbe wọn lọ pẹlu bi wọn ko ṣe le wẹ ninu ibu omi nla naa.

Leave a Reply