Ọwọ tẹ awọn oni Maruwa to pa ọlọpaa n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Eeyan mẹsan-an ọtọọtọ lọwọ awọn agbofinro tẹ n’Ibadan fun ẹsun ipaniyan nikan. Eyi ko ṣẹyin bi wọn ṣe ni wọn lu ọlọpaa kan pa nigboro Ibadan lọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii.

Ọga agba tuntun fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Adebọwale Williams, lo fidi iroyin yii mulẹ ninu ipade oniroyin akọkọ to ṣe pẹlu awọn akọroyin lolu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa to wa laduugbo Ẹlẹyẹle, n’Ibadan, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

CP Williams sọ pe ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (33) kan, Ṣẹgun Akinade to jẹ awakẹkẹ NAPEP, leku ẹda to da laasigbo ọhun silẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ “Ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ aarọ ọjọ kẹsan-an, oṣu to kọja, lawọn ọlọpaa teṣan Challenge ti wọn n mojuto irinajo ọkọ atawọn nnkan irinṣẹ mi-in loju popo laduugbo New Garrage, n’Ibadan, da Ṣẹgun Akinade duro nitori pe o wa ọkọ di oju ọna. Nitori ki wọn ma baa mu un lọ si teṣan lo jẹ ko dibọn bii ẹni pe oun daku.

“Awọn awakẹkẹ Maruwa ẹgbẹ ẹ to ri i, wọn ro pe o ti ku ni, ni wọn ba ṣuru bo ọlọpaa mejeeji to n ṣiṣẹ wọn jẹẹjẹ, wọn bẹrẹ si i lu wọn. Wọn si ṣe bẹẹ lu ọkan ninu awọn agbofinro to n jẹ Oluniyi Bamidele pa.

“Akẹgbẹ ẹ, Afọlabi Abiọla, ti ori ko yọ lo lọọ royin ohun to ṣẹlẹ ni teṣan wọn. Loju-ẹsẹ ti DPO teṣan yẹn gbọ lobinrin naa ti sare debẹ, to si ba Bamidele ninu agbara ẹjẹ loju titi nibẹ.

Kia lo ti ta mọra, ti oun atawọn ọmọ ẹ si bẹrẹ iwadii alagbara lori iṣẹlẹ yii. Nigbẹyin, ọwọ tẹ awọn ti wọn fura si pe wọn huwa ọdaran naa”.

Orukọ awọn afurasi ọdaran ọhun ni Oyebamiji Moses, ẹni ọdun mejilelogun (22); Afeez Akinpẹlu, ẹni ọdun mẹrindinlogoji (36); Ṣẹgun Joseph, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (27); Dauda Adekunle, ẹni ọgbọn (30) ọdun; Lukman Yisa, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn (31); Usman Salami, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn (26); Adewale Olubọdẹ, ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28); Mosuru Jimoh, ẹni ọdun mẹtalelogun (23) ati Ṣẹgun Akinade funra ẹ to da wahala naa silẹ.

Laipẹ rara lawọn afurasi ọdaran yii yoo foju ba ile-ẹjọ gẹgẹ bi ọga agba awọn ọlọpaa tuntun naa ṣe fidi ẹ mulẹ.

Leave a Reply