Nibi ti wọn ti n y’ayọ pe wọn kẹkọọ-jade, akẹkọọ mẹrin ku sinu omi okun l’Ekoo

Inu ipayinkeke lawọn eeyan agbegbe Lekki, nipinlẹ Eko, wa bayii lẹyin tawọn ọmọ mẹrin kan ri sinu omi Elegushi (Elegushi Beach), lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lasiko ti wọn n luwẹẹ ninu omi naa.

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe awọn akẹkọọ-jade ileewe girama Kuramo Senior College, to wa ni Lekki, mẹwaa kan ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹrinla si mẹẹẹdogun, ni wọn gba etiku lọ lati ṣe ajọyọ pe awọn pari iwe mẹwaa ati idanwo aṣekagba ọlọdun mẹwaa, iyẹn WAEC.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ to n mojuto eti okun Elegushi, Oloye Ayuba Elegushi, sọ ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, pe awọn ọmọ yẹn ko ṣe iforukọsilẹ, ọna to tọ si kọ ni wọn gba wọle sibẹ.

O fi kun un pe, agbegbe ibi ti oju o to ni etikun naa ti ki i ṣe gbogbo eeyan lo le debẹ, tawọn paapaa ki i fi bẹẹ ṣe amojuto lori ẹ niṣẹlẹ naa ti waye, ki i ṣe ojutaye ti gbogbo eeyan n ri.

O ni, “A ti kọkọ le wọn kuro lapa ibi ti wọn ti fẹẹ wẹ ni eti okun naa, ni wọn ba tun gba ibomi-in lọ ti ki i ṣe ti iru wa, ogiri wa. Ọkan ninu awọn ọmọ eeyan wa, Abass, lo ko wọn wa si lati ileewe wọn, awọn ọmọ yẹn naa si tẹle e.

“Wọn ko sanwo iwọle si eti okun yii rara. Abass lo ẹsẹ pe nnkan kan naa ni wa lati gbe wọn gba ibomi-in wọle”.

Niṣe ni awọn ọmọ tomi gbe lọ yii n kegbajare pe ki awọn eeyan gba awọn bomi ṣe n wọ wọn lọ.

Elegushi ṣalaye pe awọn ẹṣọ to maa n dena iṣẹlẹ ijamba to wa nibẹ sare bẹ somi, wọn si ri awọn mẹfa ko jade lẹsẹkẹsẹ.

“Ninu awọn mẹfa ti wọn ri ko jade, awọn kan ti fẹsẹ fẹ ẹ ka too debẹ. A ṣaa ri meji ninu wọn mu, a si ti lọọ fa awọn meji yẹn le awọn agbofinro lọwọ ni teṣan ọlọpaa to wa ni Jakande.

“Lọwọlọwọ bayii, o ṣi ku awọn mẹrin ti a n wa gẹgẹ bi awọn eeyan yẹn o ṣe ti i ri wọn ko jade kuro ninu omi. A ti fi ọrọ naa to awọn obi wọn leti, wọn si ti yọju si agọ ọlọpaa.

“Ọkan lara awọn ọmọ ileewe yẹn naa ni Abass, a ko si ti i ri oun naa gbe jade ninu omi. O tun ku ọmọ ọkunrin kan ta o ti i ri atawọn ọmọbinrin meji”.

Agbẹnusọ yii ni awọn ọmọ meji tọwọ awọn tẹ yẹn ṣalaye fawọn ọlọpaa pe wọn le awọn kuro lagbegbe etikun naa ko too di pe awọn yọ lọ si apa ibomi-in ti ki i ṣe fun ẹnikẹni.

Elegushi tun ṣalaye siwaju si i pe, “Wọn kọ ọ kalẹ sinu ọrọ ti wọn gba kalẹ lẹnu wọn pe wọn le awọn nibi akọkọ tawọn kọkọ gba lọ. Abass ni ki wọn ma ṣeyọnu pe oun maa ko wọn lọ si apa ibomi-in ni biiṣi yẹn. O pada waa ko wọn lọ si ikangun biiṣi, nibi toju gbogbo eeyan”.

Alukooro ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, ti fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, o si fi kun un pe, iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹu.

Ninu ọrọ ẹ lo ti ni, “Lati ileewe Kuramo College, ni Lekki, lawọn ọmọ yẹn ti wa. Awọn mẹrin ni wọn o ti i ri bayii. Awọn ọkunrin meji ati obinrin meji. Gbogbo ipa ni a si n sa lati ri oku wọn gbe jade bo tilẹ jẹ pe a ko ti i ribi yọju si awọn obi awọn ọmọ ti nnkan ṣẹlẹ si naa”.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ eto irinna oju omi nipinlẹ Eko (Lagos State Waterways Authority), Saheed Adesanya, ṣalaye pe oun maa ṣewadii lori iṣẹlẹ naa koun le mọ bi ọrọ ọhun ṣe jẹ, o si ṣeleri lati fi to awọn oniroyin leti ni kete to ba ti pari iwadii.

 

Leave a Reply