Nitori ati gba kaadi idibo, ijọba Eko kede isinmi ọlọjọ mẹrin lẹnu iṣẹ

Monisọla Saka

Latari ati ri i pe gbogbo awọn olugbe ipinlẹ Eko ti wọn ti to lati dibo gba kaadi idibo alalopẹ wọn ni imurasilẹ de ibo ọdun to n bọ, Gomina ipinlẹ Eko, Gomina Babajide Sanwo-Olu, ti kede ọjọ Iṣẹgun Tusidee, Ọjọruu, Wẹsidee, Ọjọbọ, Tọsidee ati ọjọ Ẹti, Furaidee, gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ.

Eyi lo ni yoo jẹ ki awọn oṣiṣẹ ijọba raaye ṣe iforukọsilẹ, ki wọn si gba kaadi idibo alalopẹ wọn ko too di ọjọ ti ijọba apapọ fi gbedeke le e fun wọn, iyẹn ọgbọnjọ, oṣu Keje, ta a wa yii.

Ọga agba awọn oṣiṣẹ nipinlẹ naa, Ọgbẹni Hakeem Muri-Okunọla, lo sọ eleyii ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aje, Mọnde. Bẹẹ lo fi le e pe oṣiṣẹ kọọkan gbọdọ pada si ẹnu iṣẹ rẹ toun ti kaadi idibo.

Gẹgẹ bi Muri-Okunọla ṣe sọ, ‘Awọn oṣiṣẹ ti wọn wa nipele kin-in-ni, ikẹta, ikeje ati ikẹẹẹdogun ko ni i lọ sibi iṣẹ lonii ọjọ Iṣẹgun, Tusidee. Ọjọruu, Wẹsidee, ni awọn to wa ni lẹburu keji, ikẹrin, ikẹjọ ati ikẹtala yoo gba isinmi. Ọjọbọ, Tọsidee, ni tawọn ipele karun-un, ikẹsan-an, ikejila, ati ikẹtadinlogun, nigba ti tawọn oni lẹburu kẹfa, ikẹwaa, ikẹrinla ati ikẹrindinlogun yoo jẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.’’

Gẹgẹ bo ṣe wa ninu atẹjade ọhun, gomina ipinlẹ Eko ṣalaye pe, “ojuṣe ẹnikọọkan lorilẹ-ede yii ni lati kopa ninu eto idibo ilu rẹ. Nidii eyi, gbogbo oṣiṣẹ ijọba la n rọ lati kopa gẹgẹ bi ibo gbogboogbo ọdun 2023 ṣe n sun mọle.

“Gbogbo awọn oṣiṣẹ ti ko ba ti i ṣe iforukọsilẹ tabi gba kaadi idibo rẹ la n fi akoko yii ke si lati ṣe bẹẹ ko too di ọgbọnjọ, oṣu Keje yii, ti iforukọsilẹ yoo wa sopin.

“Nitori eyi ni gomina ṣe faaye isinmi silẹ fawọn oṣiṣẹ ijọba lati le forukọsilẹ, ki wọn si tun gba awọn kaadi idibo wọn nijọba ibilẹ koowa wọn. Oṣiṣẹ kọọkan lo si gbọdọ pada sẹnu iṣẹ pẹlu kaadi idibo rẹ nigba ti isinmi yii ba pari.

“Labẹ eyi, a n rọ awọn ọga oniṣiro owo lati yọnda awọn oṣiṣẹ to wa lẹka wọn lawọn ọjọ ta a ti fi lede yii”.

Leave a Reply