Nitori awọn agbẹ onirẹsi mẹtalelogoji tawọn Boko Haram bẹ lori ni Borno, PDP sọko ọrọ si Buhari

Ẹgbẹ oṣelu PDP ti sọ pe ohun to foju han bayii ni pe eto aabo ti daru patapata mọ Aarẹ Muhammadu Buhari lọwọ pẹlu bi awọn Boko Haram ṣe pa awọn agbẹ onirẹsi bii mẹtalelogoji nipinlẹ Borno, lopin ọsẹ to kọja.

Ninu atẹjade kan ti Ọgbẹni Kọla Ọlọgbọndiyan fi sita lo ti sọ pe ko si ani-ani kankan, eto aabo orilẹ-ede yii ko ye ẹgbẹ oṣelu APC to n dari akoso Naijiria mọ, bẹẹ lọrọ ọhun paapaa ti daru mọ Buhari lọwọ patapata.

O ni o jẹ ohun to buru pupọ bi awọn Boko Haram ṣe kọ lu awọn agbẹ ọhun lagbegbe Zabarmari, nipinlẹ Borno, ati pe iṣẹlẹ naa ki i ṣe ohun ti ijọba gbọdọ fọwọ yẹpẹrẹ mu rara.

Ṣiwaju si i, o ni, bi wọn ṣe n pa awọn ọmọ Naijiria nipakupa yii fi ijọba Buhari han gẹgẹ bIi eyi ti ko kun oju oṣunwọn to lati daabo bo ẹmi ọmọ NaijIria ati dukia wọn.

“Ninu ibanujẹ ọkan ni ẹgbẹ oṣelu PDP wa, bi a ṣe n gbọ iroyin ibanujẹ kaakiri orilẹ-ede yii, bẹẹ ni ijọba Buhari ko wa ọna abayọ si iṣẹlẹ to n gba omije loju eeyan lojoojumọ yii.”

Ologbọndiyan fi kun ọrọ ẹ pe pẹlu ariwo ti Gomina ipinlẹ Borno, Baba Gana Zulum, n pa ni gbogbo igba nipa eto aabo ti ko munadoko to lagbegbe ọhun, sibẹ, ijọba Buhari ko ka ọrọ ọhun kun rara, ti ẹmi si n ṣofo lojoojumọ.

O ni ohun to foju han bayii ni pe orilẹ-ede Naijiria ti wa nipo ti ko si adari kankan mọ, ti ohun gbogbo kan n lọ ṣaa bii kẹkẹ ologeere.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu PDP yii sọ pe, “O jẹ ohun to ku diẹ kaato bi ijọba APC ṣe n dari orilẹ-ede yii, to jẹ pe ti iṣẹlẹ kan ba ti ṣẹlẹ, niṣe ni awọn ọmọ Buhari a maa gbe awọn akọle oriṣiriiṣii lati fi ṣapejuwe bọrọ ọhun ṣe ka a lara si, ṣugbọn ti igbesẹ gidi kan bayii ko ni i waye lati fopin si awọn iṣẹlẹ aburu to n ko awọn ọmọ Naijiria sinu ewu. Bẹẹ lawọn janduku Boko Haram paapaa ko dawọ iṣẹ ibi wọn duro, bi wọn ṣe n kọ lu ileeṣẹ ṣọja, bẹẹ ni wọn n kọ lu mọtọ akọwọọrin gomina, ti wọn tun lọọ kọ lu awọn agbẹ, ti wọn si bẹ wọn lori lọ bii ẹran.”

Wọn ni dipo ki Buhari jade, ko ṣiwaju lati dojukọ awọn Boko Haram to n ko awọn eeyan Naijiria sinu ewu yii, niṣe lo gbe ara ẹ pamọ sinu Aso Rock, toun n jaye tiẹ nibẹ, ti ọpọ ẹmi ọmọ Naijiria si wa ninu ewu.

Wọn ti waa ke si Buhari pe ko gba ilu Zabarmari, nipinlẹ Borno, lọ lati lọọ ba awọn eeyan ọhun kẹdun, ko si tibẹ gbe igbesẹ bi opin yoo ṣe deba wahala awọn a-gbebọn-kiri yii.

 

 

Leave a Reply