Nitori ẹsun ifipabanilopọ, awọn alaṣẹ Fasiti KWASU le olukọ kan danu

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn alaṣẹ Fasiti KWASU (Kwara State University), Malete, ti le olukọ kan, Pẹlumi Adewale, danu, fẹsun pe o fẹẹ fipa ba akẹkọọ kan, Tosin Adegunsoye, lo pọ nileewe ọhun.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni Ọga agba ni Fasiti KWASU, Ọjọgbọn  Mustapha Akanbi, fi iroyin naa lede fun awọn oniroyin nibi ipade akọroyin ti ọga agba ọhun pe lati fi sami ayẹyẹ ikẹkọọ-jade awọn akẹkọọ ti wọn n jade lọdun yii, ẹlẹẹkẹjọ ati ikẹsan-an iru ẹ.

Akanbi ni awọn ti le Adewale danu, o si ti kuro lara ọṣiṣẹ ileewe KWASU, tori pe o fẹẹ sọ ileewe naa ni orukọ buruku. Ni bayii, awọn ẹṣọ alaabo ti tẹwọ gba iṣẹlẹ yii, wọn si ti gbe ọkunrin naa lọ si ile-ẹjọ. 

Ọjọ kọkanla, oṣu kẹsan-an, ni wọn wọ Adewale lọ siwaju ile-ẹjọ Majistreeti kan niluu Ilọrin, fẹsun ifipabanilopọ ati iwa ọdaran miiran to fara pẹ ẹ, ninu eyi ti wọn ni Adewale pe Tosin Adegunsoye to jẹ akẹkọọ-binrin, to si sọ fun un pe to ba fẹ yege idanwo nibi iṣẹ rẹ, ko wa si inu yara olukọ naa to wa ni Opopona Taoheed, ni Basin, niluu Ilorin, nibi ti yoo ti ni ibalopọ pẹlu rẹ, ti yoo si fun un ni ibeere ati idahun, ti ọmọbinrin ọhun yoo fi le tun idanwo rẹ ṣe. Ṣe oun ko kuku mọ pe Adegunsoye ti dẹ panpẹ kalẹ, to si mu Adewale lọrun ọwọ. 

Onidaajọ Ibrahim Mohammed, gba beeli Adewale pẹlu ẹgbẹrun lọna igba Naira, to si sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kẹjọ, oṣu Kejila, ọdun yii. 

Leave a Reply