Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Adajọ Muhammed Sani tile-ẹjọ giga kan ni Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti sọ Oyedotun Adebayọ Adebọwale, akẹkọọ Kwara Poli sẹwọn ọdun meji fẹsun pe o n lu jibiti lori ẹrọ ayelujara tawọn eeyan mọ si ‘Yahoo’.
EFCC lo wọ afurasi naa lọ siwaju Onidaajọ Sani, fẹsun pe o ti lu awọn eniyan ni jibiti owo to to miliọnu lọna mọkanlelogun Naira (21 million) to si tun fi orukọ iya rẹ ra mọto Toyota Camry kan. Olujẹjọ naa si gba pe loootọ loun jẹbi ẹsun ti EFCC fi kan an.
Nigba ti Adajọ Sani n gbe idajọ rẹ kalẹ, o ni lẹyin ti oun ti ṣe ayẹwo finni finni lori awọn ẹri ti ajọ EFCC ko siwaju ile-ẹjọ, ti olujẹjọ naa ti gba pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, ki Oyedotun Adebayọ Adebọwale lọ ṣẹwọn ọdun meji tabi ko san owo itanran ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira (#300,000), ki iPhone to n lo lati fi ṣiṣẹ aburu naa, ẹgbẹrun lọna ọọdunrun lelaadọta Naira (#350,000) ti wọn ba lọwọ rẹ, to fi mọ mọto ayọkẹlẹ Toyota Camry ko di tijọba apapọ.