Nitori irẹsi ilẹ okeere: Onifayawọ meji ku, aṣọbode ati ṣọja fara gbọta l’Ọja-Ọdan

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Eeyan meji ti wọn jẹ onifayawọ ni wọn pade iku ojiji l’Ọjọbọ, ọjọ kẹfa, oṣu karun-un yii, bẹẹ ni awọn aṣọbode mẹrin ati ṣọja kan fara gbọta ibọn laarin ilu Ọja-Ọdan, nipinlẹ Ogun, nigba ti wọn doju ija kọ ara wọn nitori irẹsi ilẹ okeere.

Yatọ sawọn aṣọbode ati ṣọja to fara gbọta yii, awọn ara ilu marun-un nibọn tun ba ninu ikọlu naa, nibi ti wọn ti n ba awọn aṣọbode ko irẹsi sọkọ nibọn ti ba wọn.

Ohun to fa wahala gẹgẹ ba a ṣe gbọ ni pe awọn aṣọbode lọ sile ikẹrusi tawọn onifayawọ ko apo irẹsi ilẹ okeere rẹpẹtẹ si, wọn si ko okoolelọọdunrun (320) apo irẹsi jade nibẹ.

Nibi ti wọn ti n ko irẹsi naa jade lawọn kan ti de pẹlu ihamọra ogun, awọn onifayawọ atawọn ọmọ ita ni wọn gẹgẹ bi Alukoro Kọstọọmu nipinlẹ Ogun, Hammed Oloyede, ṣe sọ.

O ni nibi tawọn kọsitọọmu atawọn eeyan kan to n ran wọn lọwọ ti n ko apo irẹsi naa jade lawọn to de togun-togun naa ti ṣina ibọn bolẹ, ti wọn n yin in lakọlakọ, eyi si fẹrẹ to wakati kan ko too wa sopin.

Ibọn awọn onifayawọ naa ba awọn kọsitọọmu mẹrin, ṣọja kan atawọn araalu marun-un ti wọn kun wọn lọwọ lasiko ti wọn n ko apo irẹsi naa jade.

Alukoro aṣọbode Ogun ṣalaye pe awọn eeyan oun naa da ibọn ti wọn n yin fun wọn pada, wọn si pa meji ninu awọn onijagidijagan ọhun. Bẹẹ lo ni awọn mi-in ninu wọn fara gbọta ibọn, ti wọn si gbe ọta ibọn sa lọ.

Ẹnikan ti wọn pe orukọ ẹ ni Taiye Kujo lawọn aṣọbode ri mu ninu awọn onifayawọ ọhun, wọn si gba ọkada mẹfa tawọn onifayawọ naa fi ko irẹsi wọ ile ikẹru si yii.

Awọn aṣọbode pada ri awọn irẹsi naa ko lọ, wọn ko ọkada mẹfa naa pẹlu lọ si ‘Custom House,’ to wa n’Idiroko.

Oloyede waa sọ pe ohun tawọn onifayawọ rawọ le yii ko le pe wọn rara, o ni yoo wulẹ tun mu ọta to nipọn wa laarin awọn kọsitọọmu pẹlu wọn ni. Yoo si tun ro awọn lagbara si i lati koju wọn.

Iṣẹ ṣi n lọ lati ri awọn onifayawọ to sa lọ pẹlu ọta ibọn naa mu, awọn aṣọbode lawọn yoo wa wọn ri dandan.

Leave a Reply