Nitori obinrin, Naso gun ara ile rẹ pa loju oorun l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọkunrin ọmọ ibo kan tawọn eeyan mọ si Naso ti n sọ tẹnu rẹ lọwọ lọdọ awọn ọlọpaa to n ṣe iwadii iwa ọdaran nipinlẹ Ondo lori idi to fi binu gun ara ile rẹ kan, Ṣeyi, pa nitori ọrọ obinrin lasan.

Ọsẹ to kọja yii ni wọn niṣẹlẹ naa waye lagbegbe Messiah High School, niluu Akurẹ, nibi ti oloogbe ati iyawo rẹ gba ile si.

Naso ni wọn lo lọọ ka ọkunrin to wa lati ilu Ita-Ogbolu, nijọba ibilẹ Iju/Ita-Ogbolu, ọhun mọ ibi to sun si ninu yara rẹ, to si gun un pa.

ALAROYE gbọ pe ija kekere kan ti kọkọ waye laarin awọn mejeeji lọjọ naa lori ẹsun ti Ṣeyi fi kan Naso pe o kan iyawo oun labuku pẹlu bo ṣe bu u ni gbangba.

Ọrọ yii lo ṣokunfa bawọn mejeeji ṣe sọrọ kobakungbe sira wọn kawọn eeyan too ba wọn da si i. Awọn aládùúgbò parọwa fawọn mejeeji ki wọn bomi suuru mu, lai mọ pe ọrọ yii ko tan rara ninu Naso.

Oru ọjọ kan naa ni afurasi ọhun pada lọọ ka ọmọkunrin naa mọ’le, to si gun un lọbẹ pa mọ ibi to sun si.

Leave a Reply