Nitori owo atunṣe oju-ọna, kọmiṣanna Arẹgbẹṣọla ati ti Oyetọla gbena woju ara wọn l’Ọṣun

Florence Babaṣọla

Owo tijọba apapọ san pada funjọba ipinlẹ Ọṣun lori atunṣe awọn ojupopo to jẹ tijọba apapọ ti da ariyanjiyan silẹ laarin awọn ọmọ-ẹyin gomina ana, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ati ti Gomina Gboyega Oyetọla bayii.

Nibi eto kan ni kọmiṣanna fun ọrọ idile (Home Affairs) laye ijọba Arẹgbẹṣọla, Ọmọọba Sikiru Ayedun, ti sọ laipẹ yii pe biliọnu mejidinlaadọta naira (#48bn) ni Gomina Oyetọla ti gba pada latọdọ ijọba apapọ lori awọn oju-ọna ti wọn ti ṣe.

Ayedun ṣalaye pe owo yii, eleyii to ni Arẹgbẹṣọla ṣiṣẹ rẹ silẹ fun un, ni Oyetọla n lo lati fi san ẹkunrẹrẹ owo-oṣu awọn oṣiṣẹ, to si pa aṣiri yii mọ fun awọn araalu.

Ṣugbọn Kọmiṣanna feto iṣuna lọwọlọwọ bayii, Ọmọọba Bọla Oyebamiji, ko jẹ ki ọrọ naa tutu rara, o ni aturọta bii elubọ ni Ayedun, nitori ohun ti ko ridi lo n sọ fun awọn araalu.

O ni irọ to jinna soootọ ni ọrọ ti Ayedun sọ ọhun, eleyii to si le ṣi awọn araalu lọna, to si tun le da wahala ati iyapa silẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Oyebamiji ṣalaye pe biliọnu lọna mejidinlogoji naira (#38bn) gan-an ni gbogbo owo awọn oju-ọna ijọba apapọ tijọba Arẹgbẹṣọla ṣe, bawo waa ni ijọba Ọṣun yoo ṣe gba ju owo iṣẹ to ba ijọba apapọ ṣe lọ?

O fi kun ọrọ rẹ pe, lọwọlọwọ bayii, ẹẹmẹta ọtọọtọ nijọba apapọ ti fi lara owo naa ranṣẹ sijọba ipinlẹ Ọṣun, apapọ mẹtẹẹta si jẹ biliọnu mejila o din miliọnu kan naira (#11.9bn), eyi to si jẹ owo awọn iṣẹ ti awọn kọngila ti ṣe yọri.

O ni ori awọn oju-ọna mẹrin ọtọọtọ tijọba Oyetọla jogun latọdọ ijọba Arẹgbẹṣọla ni awọn na owo ọhun le lori yatọ si owo-oṣu ti Ayedun sọ.

Oyebamiji waa ke si gbogbo awọn araalu lati maa wadii ohun gbogbo dajudaju, ko too di pe wọn aa di eyi to jẹ otitọ mu, ti wọn aa si maa polongo rẹ kaakiri ki alaafia le tubọ maa jọba nipinlẹ Ọṣun.

Leave a Reply