Nitori Sunday Igboho, Kunle Adegbitẹ sọrọ sawọn oṣere ẹgbẹ ẹ

Faith Adebọla, Eko

Ọkan-o-jọkan ọrọ iwuri lawọn eeyan fi n gboṣuba lasiko yii fun gbajugbaju ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti inagijẹ rẹ n jẹ Sunday Igboho, titi kan awọn onitiata ilẹ wa ni wọn n ṣe sadankata ọkunrin naa, fun bo ṣe huwa lasiko tawọn ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ wa lọọ ṣakọlu sile rẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, yii.

Irawọ oṣere ilẹ wa kan, Kunle Adegbitẹ sọrọ nipa iṣẹlẹ yii, o kọ ọ soju opo ayelujara ẹ lọjọ Ẹti, Furaidee yii, pe:

“Akọni ọkunrin ni ẹ o, Igboho Ooṣa (Sunday Igboho), mo mọ pe to ba jẹ pe o fẹẹ ba awọn ẹṣọ DSS atawọn ṣọja ti wọn wa sile ẹ yẹn ja ni, o mọ ohun ti o le ṣe, ṣugbọn nitori awọn alaimọwọ-mẹsẹ ti wọn n gbe ile ẹ lo o ṣe gbẹsan, Akọni Igboho Ooṣa, Ọlọrun maa wa pẹlu ẹ lasiko to le koko yii, Majasọla, ire nla.

Oṣere naa tun bẹnu atẹ lu ihuwasi awọn eeyan, paapaa, awọn Yoruba lori ọrọ yii, o ni wọn ti dakẹ ringindin ju, oun o si reti pe kiru nnkan bayii ṣẹlẹ, kawọn eeyan ma sọrọ nipa ẹ bo ṣe yẹ.

Kunle ni, mo ti n ṣakiyesi ẹrọ ayelujara latigba ti iṣẹlẹ yii ti waye, mo fẹẹ mọ bi awa Yoruba ṣe maa ṣatilẹyin fun Sunday Igboho, ṣugbọn o ya mi lẹnu pe gbogbo yin kan dakẹ fẹmu ni, ṣe ba a ṣe fẹẹ ja fominira wa ree? Ijo “maa jo lọ, mo n wẹyin ẹ’, la n jo fun Sunday. Loootọ, ko sẹni to le ba ijọba ja, tori ẹ loun naa ko ṣe ba wọn ja, awọn eeyan ẹ, awa Yoruba, lo n ja fun, ko ṣe ju bẹẹ lọ, ṣugbọn gẹgẹ bii ọmọ Yoruba, ẹ jẹ ka ṣe koriya fun Sunday Igboho. Boya a ti pade ẹ ri tabi a o tiẹ ri i ri, o yẹ ka ṣugbaa ẹ lasiko yii, niṣe lo yẹ ki atẹ ayelujara maa ho ṣọṣọ fun fọto ẹ ati awọn ọrọ loriṣiiriṣii lati fi aduroti wa han. Eyi ni ko ni i jẹ ko ro pe awọn eeyan ko si lẹyin oun. Ẹyin ọmọ Yoruba, ẹ jẹ ka ronu o.

Si ẹyin onitiata ẹlẹgbẹ mi, iyẹn ni pe ẹyin eeyan yii le dakẹ lori ọrọ Sunday Igboho? O ya mi lẹnu o. Mo mọ diẹ lara yin to ti janfaani ọkunrin yii o, ti Sunday Igboho ti ṣe nnkan gidi fun, tabi fun lẹbun loriṣiiriṣii, ẹ o tiẹ le fihan pe ẹ mọyi ẹ lasiko ipọnju yii, ṣe o daa bẹẹ? Igba iponju la a m’ọrẹ, emi o gba kọbọ lọwọ Sunday Igboho ri, ṣugbọn mo fẹran ẹ pupọ tori ẹni ti ko nifẹẹ irẹjẹ ati abosi ni, ki i ṣe onimọtara-ẹni ẹda rara, adurotini ti ki i yẹsẹ si ni. Mo reti pe asiko ree to yẹ ka fi aduroti ati ifẹ wa han si i. Ẹ ma binu o, ọrọ amọran ni mo mu wa o, bi emi si ṣe ri i niyẹn o.”

Bi Kunle Adegbitẹ ṣe pari ọrọ rẹ ni ọgọọrọ awọn ololufẹ ẹ atawọn ẹlomi-in ti fi ọrọ ati ami ranṣẹ sori ikanni instagiraamu ọhun, wọn ni ọrọ pataki lo sọ, wọn lo ri ọrọ naa sọ gidi ni.

Leave a Reply