Nitori to yọ ọga agba ileewe naa nipo, ẹgbẹ oṣiṣẹ LAUTECH binu si Makinde

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ẹgbẹ awọn olukọ Fasiti nilẹ yii, iyẹn Academic Staff Union of Universities (ASUU), ẹka Fasiti LAUTECH, to wa niluu Ogbomọṣọ; ati ẹgbẹ awọn agba oṣiṣẹ ni fasiti naa, Senior Staff Association of Nigerian Universities (SSANU) ti bu ẹnu atẹ lu bi Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ṣe yọ ọga agba fasiti ọhun, Ọjọgbọn Michael Olufisayọ Ologunde  danu nipo.

Ninu atẹjade ti awọn adari ẹgbẹ mejeeji ọhun fi ṣọwọ sawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni wọn ti fẹdun ọkan wọn ọhun han. Wọn ni niṣe ni gomina kan deede yọ ọjọgbọn naa nipo lai tẹle  ilana to tọ lori igbesẹ ọhun. Bakan naa ni wọn lo fọ ẹgbẹ awọn akẹkọọ si meji, ko si jẹ ki ohun awọn ọmọọleewe naa ṣọkan mọ.

Bo tilẹ jẹ pe Gomina Makinde ko sọ idi to ṣe fọwọ osi juwe ile fun Ọjọgbọn Ologunde, igbagbọ ọpọ awọn oṣiṣẹ fasiti imọ ẹrọ naa ni pe nitori pe ọjọgbọn naa gbiyanju lati kọyin awọn oṣiṣẹ-fasiti yii sijọba ipinlẹ Ọyọ ni gomina ṣe kanra yọ ọ nipo.

Ni nnkan bii ọsẹ meloo kan sẹyin ni gomina yii fẹsun kan ọjọgbọn agba Fasiti LAUTECH ti wọn rọ loye yii pe oun lo wa nidii ija ti awọn oṣiṣẹ ileewe ọhun ja laipẹ yii, ati pe dandan ni ki ijọba ṣafikun owo-oṣu awọn.

Alaye to ṣe lọjọ naa lọhun-un ni pe nigba ti awọn oṣiṣẹ LAUTECH bẹrẹ ija fun ẹkunwo yii, oun gbe igbimọ oluwadii kan dide lati mọ idi ti wọn ṣe faake kọri pe awọn ko fara mọ iye ti ijọba n fun awọn gẹgẹ bii owo-oṣu mọ, ṣugbọn si iyalẹnu oun, awọn oluwadii ọhun ja bọ fun oun pe ọga agba Fasiti naa lo kọ awọn oṣiṣẹ wọnyi lati ja fun ẹkunwo, o ni ohun to ba fi le mu ki ijọba ipinlẹ Ọyọ san biliọnu mẹjọ naira fun ipinlẹ Ọṣun fun yiyọ ti wọn yọwọ ipinlẹ Ọṣun kuro ninu awọn to ni ileewe naa, o yẹ ki wọn le ṣafikun owo-oṣu awọn naa.

Ju gbogbo ẹ lọ, ẹgbẹ ASUU ati SSANU ti sọ pe gomina ko lagbara lati yọ ọga agba fasiti nipo bẹẹ. Wọn ni ọna kan ṣoṣo ti gomina le gba ṣe bẹẹ ni ki igbimọ awọn alaṣẹ fasiti yii ti awọn oloyinbo n pe ni Governing Council ba sọ pe iru alakooso bẹẹ kọ ṣaye ire, ti wọn si dabaa pe ki gomina yọ ọ nipo.

Leave a Reply