Olajide Kazeem
Loruganjọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii ni awọn janduku kan ji mọto Hilux Oluwoo ilẹ Iwo, Ọba Abdul-Rasheed Akanbi, gbe niluu Eko.
Agbẹnusọ fun ọba alaye naa, Ọgbẹni Alli Ibraheem lo fi ikede ọhun sita. Ohun to si sọ ni pe otẹẹli kan ti wọn n pe ni Toilam Royal Hotel, lagbegbe Igboṣere, nigboro Eko, ni wọn ti ji mọto ọhun gbe sa lọ.
Ọda funfun ni wọn fi kun un, orukọ Ọba Adewale Akanbi ni wọn kọ sara ẹ gẹgẹ bii ami idanimo ọkọ naa.
Hmmmmm,ategun to wole gbe ketepe ogi ki oniyefun ma safira
Olè tó gbé kàkàakí oba kòsí ibi ti o fón.